Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Oluṣọla Babajide Sanwo-Olu, ti kede pe lati asiko yii, ẹṣẹ nla ni fun ileewe eyikeyii nipinlẹ Eko, ibaa jẹ tijọba abi ti aladaani, lati gba ọmọ ti ko ti i pe ọdun mejila lọjọ-ori sileewe girama, wọn lawọn alaṣẹ ileewe bẹẹ maa fẹnu fẹra bii abẹbẹ ni.
Ninu atẹjade kan lati ọfiisi Akọwe agba lẹka eto ẹkọ, eyi ti Abilekọ A. A. Adebọwale buwọ lu lorukọ Akọwe agba, o ni ofin tuntun yii ti bẹrẹ iṣẹ lati saa ikẹkọọ ọdun 2021 yii, paapaa bawọn akẹkọọ tuntun ṣe n wọle sileewe girama lọsẹ yii. Sanwo-Olu ni o pọn dandan fun ijọba Eko lati gbe igbesẹ yii latari bawọn ọmọ keekeekee ṣe n rọ lọ sileewe giga nigba tọjọ-ori wọn ṣi kere jọjọ, to jẹ ileewe pamari lo ṣi yẹ ki wọn wa.
Ijọba ni ẹnikẹni to ba lufin yii fun igba akọkọ yoo sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira (N50,000), ṣugbọn tonitọhun ba tun lufin naa lẹẹkeji, owo itanran rẹ yoo jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) pẹlu lẹta ikilọ tawọn ma fun un.
Ẹni ti ajere ba waa ṣi mọ lori lẹẹkẹta ko ni i sanwo itanran o, ileewe rẹ lawọn yoo ti pa, awọn yoo si gba iwe-aṣẹ to fi n ṣiṣẹ lọwọ rẹ, tabi kawọn le e danu lẹnu iṣẹ ọba, to ba jẹ ileewe ijọba ni.
Atẹjade naa ṣalaye fawọn obi, ọpọ iṣoro to maa jẹ yọ nigba tawọn ọmọ ti ko ti i dagba to ba lawọn fẹẹ wọle si kilaasi JSS 1, o lawọn ti fun ajọ SUBEB, iyẹn State Universal Basic Education Board, laṣẹ lati ri i pe wọn ṣayẹwo awọn ọmọ to fẹẹ wọle naa daadaa, ki wọn si ri pe awọn ileewe tẹle ilana ati ofin tijọba ṣe yii.
O ni gbogbo ọna nijọba ipinlẹ Eko n ṣan lati ri i pe eto ẹkọ tubọ sunwọn si i jake-jado ipinlẹ naa, apa o si ni i kun ijọba lati ṣe bẹẹ, tori naa kawọn obi, olukọ, alaṣẹ ileewe ati awọn akẹkọọ naa fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.