Faith Adebọla
Bi ko ba nidii, obinrin ki i jẹ Kumolu, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde sọ pe ki i ṣe pe oun kan dide wuya lati lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, o ni tori ifẹ toun ni si orileede yii loun ṣe fẹẹ lọọ kun ẹgbẹ naa lọwọ lati ja fun iṣọkan Naijiria, kawọn si jọ koju awọn ipenija torileede naa n koju lọwọlọwọ.
Fani-Kayọde sọrọ yii ni kete to kuro lọdọ Aarẹ Muhammadu Buhari, nibi ti Alaga afun-n-ṣọ ẹgbẹ APC to tun jẹ Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni, ti ṣafihan oun ati Gomina ipinlẹ Zamfara, Alaaji Bello Matawale, gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ tuntun.
Minisita fun igbokegbodo irinajo ofurufu nigba kan, Fani-Kayọde, ba awọn oniroyin sọrọ l’Abuja, o ni lilọ sinu ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) lasiko yii ko gbọdọ ya ẹnikẹni lẹnu, tori oun wa lara awọn to jẹ ipilẹ fun ẹgbẹ oṣelu naa nigba ti wọn fẹẹ da a silẹ lọdun mẹjọ sẹyin, awọn jọ da a silẹ ni 2013 ni, boun ba si pada sẹgbẹ naa bayii, ile loun pada si.
Lori idi to fi pada, ọkunrin naa ni: “Koko to wa nibẹ ni pe mo ro o pe asiko niyi lati ṣe ohun to tọ, lati fi Naijiria sipo akọkọ, ati lati mọyi isapa tawọn eeyan ti ṣe lori ọrọ aabo, wahala awọn janduku agbebọn, ti awọn eeṣin-o-kọ’ku, paapaa lọdun diẹ sẹyin, pẹlu akitiyan lati mu ki Naijiria wa papọ lodidi. Mo ri i pe asiko niyi lati ṣiṣẹ papọ, ka pari aawọ, ki orileede yii le ni ilọsiwaju.
O ṣe pataki fun wa lati lati mọyi nnkan daadaa ta a ba ri to n ṣẹlẹ, ki i ṣe aidaa ni ka kan maa rannu mọ ni gbogbo igba, ta a a ba si ri i pe asiko to, o yẹ keeyan yi ero rẹ pada, ko kun awọn ti wọn n ṣiṣẹ ilọsiwaju lọwọ.
Eyi o tumọ si pe ka sọ ara wa di ọta ẹnikẹni o. Gbogbo wa la si le jọ ṣiṣẹ pọ, ibaa jẹ inu ẹgbẹ oṣelu mi-in la wa, boya PDP tabi omi-in, boya ẹsin kan naa tabi omi-in, ẹya kan naa tabi omi-in, koko ta a gbọdọ fi sọkan ni pe Naijiria ko gbọdọ daru, ko gbọdọ tuka, ki oju le ti awọn to n fẹ ka maa ba ara wa ja.
Inu mi dun lati wa lọdọ Aarẹ Buhari, inu ẹ dun si mi, o si ba mi sọrọ daadaa, o fifẹ han si mi, a si jọ pinnu lati ṣiṣẹ fun ilọsiwaju Naijiria.”
Bayii ni Fani-Kayọde ṣalaye ara ẹ.