Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
O pẹ gan-an ti baba yii, Jimọh Mutaliu, ti n ba ọmọ aburo ẹ sun niluu Abẹokuta. Bi ọjọ ori ọmọbinrin naa ko ṣe ju mẹrindinlogun lọ to (16), ẹẹmeji lo ti loyun fun Jimọh, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52). Oyun ẹlẹẹkẹta lo tun ni fun ẹgbọn baba rẹ naa bayii ti aṣiri fi tu.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an yii, ni awọn ọlọpaa teṣan Adatan, l’Abẹokuta, lọọ mu Jimọh, iyẹn lẹyin ti aburo ẹ to jẹ baba ọmọ to fun loyun lọọ ṣalaye fun wọn pe ọmọ oun loyun, nigba toun si beere ẹni to fun un loyun ọhun, niṣe lo ni ẹgbọn oun, Jimọh Mutaliu, ni.
Baba ọmọ ti wọn forukọ bo laṣiiri naa tẹsiwaju pe pẹlu iwadii si i, ọmọ oun jẹwọ pe oun ti loyun meji fun baba naa ri, awọn si ti ṣẹ ẹ.
Ifisun yii lo jẹ kawọn ọlọpaa lọọ gbe Jimọh, oun si ṣalaye pe ọmọbinrin naa ko parọ mọ oun o, o ni bo ṣe ṣẹlẹ gan-an lo ṣe wi yẹn.
Jimọh sọ fawọn ọlọpaa pe o pẹ tawọn ti wa nidii erekere naa, ẹẹmeji loun ti fun ọmọ aburo oun naa loyun, oun si ṣẹ ẹ fun un nipasẹ nọọṣi adugbo kan.
Bo ti ṣalaye ẹ naa tan lawọn ọlọpaa ti taari ẹ si ẹka to n gbọ ẹjọ awọn to n ba aye ọmọde jẹ bii eyi, nitori bẹẹ ni CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn ṣe.
Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun yii waa tun kilọ fawọn obi lẹẹkan si i pe ki wọn mura si itọju awọn ọmọbinrin wọn daadaa, ki wọn maa ṣọ wọn lọwọ-lẹsẹ, ki wọn ma sọ pe famili awọn lọkunrin kan.
Ajogun sọ pe iwa ibajẹ to n ṣẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yii l’Abẹokuta ko kan famili, baba ti fun ọmọ ẹ loyun, ọkọ ti ba ọmọ iyawo ẹ lo pọ bi ọmọ ọhun ti kere to, ẹgbọn baba lo tun fun ọmọ aburo ẹ loyun yii, lẹyin to ti ṣẹ meji fun un.
Fun idi eyi, kọlọmọ kilọ fọmọ lọrọ di bayii, gẹgẹ bi atẹjade to ti ọwọ DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun jade ṣe sọ.