Florence Babaṣọla, Osogbo
Seriki Fulani nipinlẹ Ọṣun, Babatunde Ibrahim, ti sọ pe lẹyin ti awọn ṣayẹwo ofin to ta ko fifi ẹran jẹko kaakiri, eleyii ti Gomina Oyetọla buwọ lu laipẹ yii, o han gbangba pe ṣe ni yoo tubọ mu ki iṣẹ awọn rọrun.
Lẹyin ipade kan ti ọfiisi oludamọran fun gomina lori ilanilọyẹ araalu ṣe pẹlu awọn olori darandaran ati awọn agbẹ nipinlẹ Ọṣun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lati ṣalaye ofin tuntun naa fun wọn ni Seriki ti sọrọ yii.
O ni nigba ti awọn gbọ ikede nipa ofin naa lẹyin ti gomina buwọ lu u, ṣe ni aya awọn bẹrẹ si i ja, ti awọn si wa ninu ibẹrubojo.
O ni ṣugbọn pẹlu alaye kikun, ilanilọyẹ ati idaniloju ti awọn ti ni nipa ofin naa bayii, ko si ibẹru mọ, o ni gbogbo awọn darandaran ni wọn yoo tẹle alakalẹ ofin naa patapata.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Inu wa dun fun ipade yii. Ofin yii yoo mu ki iṣẹ wa rọrun. A kọkọ ro pe ṣe ni wọn fẹẹ daamu wa pẹlu ofin yẹn. Ibi la bi wa si, ibi la si dagba si. A ko ti i ri iru wahala to n ṣẹlẹ laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ lasiko yii ri.
“A maa ba awọn eeyan wa sọrọ pe ki wọn dẹkun kiko awọn ẹran wọn kaakiri ẹgbẹ titi tabi kiko wọn jẹ laarin ilu, bẹẹ ni awọn maaluu ko ni i ba nnkan oko jẹ mọ. Funra wa la maa fa ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ sofin yii le ijọba lọwọ.”
Nigba to n ba awọn darandaran naa sọrọ, Oludamọran pataki fun gomina lori ilanilọyẹ awọn araalu, Ọgbẹni Ọlatunbọsun Oyintiloye, ṣalaye pe lati daabo bo awọn darandaran ati awọn agbẹ nijọba ṣe ṣe agbekalẹ ofin naa.
O rọ wọn lati ṣiṣẹ wọn labẹ alakalẹ ofin tuntun to wa nilẹ yii, o si ṣeleri pe iṣejọba Gomina Oyetọla ti ṣetan lati daabo bo ẹtọ gbogbo awọn araalu lọwọ ikọlu lati ibikibi.