Lojiji lawọn banki ko ṣilẹkun mọ n’Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, iyẹn lati ibẹrẹ ọsẹ to pari yii, awọn eeyan to fẹẹ fowo pamọ tabi gba owo nla si n foju wina iṣoro. N lawọn kan ba n gbe e kiri pe awọn ole lo kọ lẹta sawọn ileefowopamọ naa pe awọn n bọ waa digun ja wọn lole, wọn ni ohun to jẹ kawọn banki tilẹkun niyẹn.
Bo tilẹ jẹ pe ẹsẹkẹsẹ ni DPO teṣan ọlọpaa Igbeba, n’Ijẹbu-Ode, CSP Musiliu Iṣọla Doga, ti sọ pe ki i ṣe awọn ole lo jẹ ki wọn ti banki pa, awọn eeyan kan ko tete gba eyi gbọ.
Wọn ni bawọn banki naa ko ba ri nnkan to le di ọran nla si wọn lọrun, wọn ko ni i ti ileeṣẹ ti wọn ti n rowo pa kawọn onibaara si maa daamu bayii.
CSP Doga ṣalaye pe loootọ lawọn banki ko ṣilẹkun n’Ijẹbu-Ode, ṣugbọn ki i ṣe nitori awọn ole, ẹnikẹni ko kọ lẹta kankan si wọn bawọn eeyan ṣe n gbe e kiri.
Ọlọpaa naa sọ pe aiṣilẹkun awọn banki ni lati jẹ ipinnu wọn, o ni gbogbo agbegbe Ijẹbu-Ode lawọn ọlọpaa wa ti wọn n ṣiṣẹ idaabobo lai yọ banki silẹ. To ba si jẹ ti ọkọ ologun ti wọn ko ri, Armoured personnel carriers, o ni ṣebi awọn ọlọpaa naa lo n dari ẹ, bi iyẹn ko ba si nitosi, ko tumọ si pe ko si ọlọpaa nigboro Ijẹbu-Ode.
O waa rọ awọn oṣiṣẹ banki atawọn araalu pe ki wọn fi ọkan balẹ, ko si ole kankan to kọ lẹta wa pe awọn n bọ waa fọ banki.
Bakan naa ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimọla Oyeyẹmi, ni kawọn eeyan fi ọkan balẹ. O ni ko sohun to jọ lẹta kankan lati ọdọ awọn adigunjale, ki wọn ma si ṣe tori ohunkohun kaya soke rara.
ALAROYE ba awọn eeyan kọọkan sọrọ n’Ijẹbu-Ode lori awuyewuye yii, pupọ ninu wọn sọ pe ahesọ lasan ni ti lẹta ti wọn ni awọn ole kọ wa yẹn. Wọn ni ọkọ idaboobo to maa n wa ni banki ti wọn n pe ni Armoured Personnel Carrier ti ko si lawọn banki lasiko yii lo fa a tawọn alaṣẹ banki ko ṣe ṣilẹkun, ko si le pẹ ti wọn yoo fi yanju rẹ ti wọn yoo maa ṣilẹkun pada.