Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lọwọ tẹ ọdọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Azeez, lagbegbe Oke-Solo. Papakọ ofurufu to wa ni ilu Ilọrin lo pa baba agbalagba kan si, to si wọ oku ẹ lọ sinu igbo.
Ni nnkan bii aago mọkanla owurọ ọjọ Abamẹta ni awọn to n gbe ni agbegbe Oke-Solo, kofiri Azeez, ti wọn si ri i to n wọ oku baba agbalagba kan to ṣẹṣẹ pa lọ si inu igbo kan to wa ni agbegbe naa. Ni wọn ba ra a mu, wọn si de e lokun lọwọ ati ẹsẹ, wọn si lu u bii aṣọ ofi. Wọn beere orukọ rẹ, o ni Azeez loun n jẹ, oun si n gbe ni Odo-Ire, niluu Ilọrin. Ṣugbọn ẹnikan to da a mọ sọ pe ki i ṣe Odo-Ire lo n gbe, ẹgbọn rẹ lo rẹnti ile si Odo-Ire.
Nigba ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo daadaa, o jẹwọ pe ipinlẹ Ọṣun ni oun ti wa, oun si duro sọdọ ẹgbọn oun nitori iṣẹ aburu toun fẹẹ ṣe. Ṣugbọn lilu ti wọn lu u ti pọ debii pe ko le dahun si gbogbo awọn ibeee ti wọn n bi i mọ ni wọn fa a le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.