Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Idaji kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ni ọmọkunrin yii, Rotimi Ojugbelẹ, bọ sọwọ awọn ọlọpaa loju ọna Ilaro/Owode Yewa, nipinlẹ Ogun. Awọn ọlọpaa to mu un sọ pe oko ole loun ati ikeji rẹ to sa lọ lọjọ naa ti n bọ, nitori gbogbo nnkan ọṣẹ lawọn ba lọwọ ẹ laago mẹfa aabọ idaji ọjọ yii tọwọ ba a.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, to fi iṣẹlẹ naa ṣọwọ s’ALAROYE ṣalaye pe DPO ẹkun Ilaro, CSP Ọlayẹmi Jacob, atawọn ikọ ẹ jade ni idaji naa lati ṣọdẹ awọn oniṣẹ ibi ni, nigba ti wọn n lọ ni wọn ri awọn ọkunrin meji kan lori ọkada, ọkan ninu awọn ọkunrin naa si gbe apo kan dani.
Awọn ọlọpaa da wọn duro lati beere ibi ti wọn ti n bọ ni fẹẹrẹ bẹẹ, ṣugbọn bi wọn ṣe duro bayii, niṣe ni ọkan ninu wọn sa lọ, awọn ọlọpaa ko ri i mu, ẹnikeji ti wọn ri mu ni Rotimi Ojugbelẹ yii.
Nigba ti wọn yẹ apo to gbe dani ọhun wo, awọn ọlọpaa sọ pe awọn ba ibọn ibilẹ kan nibẹ, ọta ibọn mẹsan-an ti wọn ko ti i yin wa ninu apo ọhun pẹlu foonu Samsung galaxy S8 kan, awọn foonu kekere meji ti ko ni siimu ninu, idi igbo mimu meji, aago ọwọ kan ti awọ rẹ jẹ funfun ati irinwo le lọgọta naira (460) ni wọn lo tun wa ninu apo ọhun.
Ẹka ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran ni CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn gbe Rotimi lọ, ki wọn si wa ẹnikeji ẹ to sa lọ naa ri, ki wọn le jọ foju ba kootu laipẹ rara.