Adefunkẹ Adebiyi
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 yii, Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ kan laaarọ ọjọ naa lasiko to n ka ohun to ni fawọn eeyan Naijiria bi orilẹ-ede yii ṣe pe ọdun mọkanlelọgọta. Buhari sọ pe ko sijọba to ṣiṣẹ ti oun ti ṣe laarin ọdun mẹfa toun fi jẹ Aarẹ Naijiria, o ni lati 1999 titi dasiko yii, ẹyin lọmọdiẹ n tọya lọrọ awọn ijọba yooku, wọn ko ṣiṣe to ijọba toun rara ni.
Aarẹ ṣalaye siwaju pe awọn ti wọn ko ri daadaa ti ijọba oun ti ṣe ni wọn n foju adagun odo wo o, ti wọn n sọ pe oun ko gbe nnkan kan ṣe.
“Latigba ti a ti gba akoso, ijọba yii ti mojuto awọn iṣoro wa lati isalẹ titi doke pẹlu bo ṣe jẹ pe diẹ ni ohun ti a ni lati fi gbọ bukaata wa. A oo maa tẹsiwaju lati sin orilẹ-ede yii, a oo maa tẹti sawọn eeyan wa, a oo si maa daabo bo ijọba awarawa” Bẹẹ ni Buhari wi.
O fi kun un pe aimọye aṣeyọri nijọba oun ti ṣe lati ọdun 2015 toun ti n ba kinni ọhun bọ, awọn iṣẹ naa si gbayi to jẹ ko si iṣakoso kan to ṣe iru ẹ lati 1999 ti Dẹmokiresi ti de ilẹ yii.
Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Oloogbe Umar Yar’Adua ati Ọmọwe Goodluck Jonathan lo ṣejọba Dẹmokiresi ki Buhari too de, iṣẹ awọn mẹtẹẹta ni Aarẹ papọ to ni ko to eyi toun ṣe lọdun mẹfa yii.