Adefunkẹ Adebiyi
Imọran ti lọ setigbọọ awọn eeyan ti wọn fẹran lati maa fi owo wọn ra ẹran adiẹ (chicken) ati tọki (Turkey) ti wọn n ko wa lati ilẹ okeere, to si jẹ pe inu yinyin ni wọn n ṣe awọn kinni ọhun lọjọ si fun ọjọ pipẹ ki wọn ma baa bajẹ.
Dokita Abubakar Jimọh, Alukoro ajọ NAFDAC (National Agency for Food and Drug Administration and Control) lo gbe amọran naa kalẹ nigba to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa NAN. O ṣalaye pe eroja buruku kan ti wọn n pe ni ‘Formalin’ eyi ti wọn maa n lo ni mọṣuari lati fi tọju awọn oku ki wọn ma baa maa run, ni awọn to n ko tọki ati ṣinkin yii wọ Naijiria lati ilẹ okeere n lo.
O ni kinni naa ni wọn fi n tọju rẹ ti ki i fi i bajẹ titi ti wọn yoo fi ko o debi, ti awọn eeyan ilẹ yii yoo si maa fi owo wọn ra majele lai mọ.
O fi kun un pe beeyan ba fẹẹ ra adiẹ tabi tọki, o daa ko jẹ ti ibilẹ ni tọhun yoo ra, eyi ti ko nilo yinyin, ti wọn ko si ni i fi kẹmika buruku si i.
Agbẹnusọ NAFDAC naa tẹsiwaju pe yatọ si pe majele ni awọn eeyan n fowo wọn ra, o ni owo ile to yẹ ko wulo fun Naijiria lawọn to n ra ṣinkin ati tọki inu yinyin yii n mu lọ sita.
Dokita Abubakar ṣalaye pe owo ta a fi ra tọki inu yinyin ko ni i duro ni Naijiria, ilẹ okeere lo n lọ. Bẹẹ lo si tun jẹ pe rira awọn nnkan inu yinyin yii ko ni i jẹ kawọn olokoowo adiẹ ti wọn n ṣin lọna ibilẹ gberi, nigba ti wọn ko ba rẹni ra ọja wọn.
Awọn nnkan teeyan le jẹ lai fowo ra iku bii eyi pọ, gẹgẹ bi Dokita Jimọh ṣe wi, ti yoo ṣara loore, ti yoo si pawo wọle fun Naijiria tiwa.