Aṣiri aṣofin apapọ ilẹ wa to n ṣatilẹyin fun Sunday Igboho ti tu – Abubakar Malami

Faith Adebọla

Amofin agba ilẹ wa, to tun jẹ Minisita feto idajọ, Abubakar Malami, ni afẹfẹ ti fẹ o, awọn ti ri furọ adiẹ. O ni aṣiri kan ti tu sawọn lọwọ pe ọkan lara awọn aṣofin ilẹ wa to jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin apapọ lo n kowo fun ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, o ni aṣofin naa ni onilu to n lu fun iromi Sunday Igboho to fi n jo labẹ omi.

Malami sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, niluu Abuja, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ. O ni oun o ni i darukọ ẹni ti aṣofin naa jẹ gan-an tori iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣi n lọ lori ẹ, ṣugbọn abọ iwadii igbimọ alaabo kan tijọba apapọ gbekalẹ lati tuṣu desalẹ ikoko awọn ajijagbara to gbinaya lorileede yii ti fidi ẹ mulẹ pe Sunday Igboho gba owo nla lọwọ ileeṣẹ kan, Abbai Bako and Sons, l’Abuja, to jẹ Ọgbẹni Abdullahi Umar Usman, o ni wọn si ti fẹsun kan ileeṣẹ naa pe o n ṣonigbọwọ awọn apanilaya atawọn eeṣin-o-kọ’ku.

“Ọgbẹni Abdullahi Umar Usman ni ajọṣepọ olokoowo pẹlu Surajo Abubakar Muhammad, ẹni ti wọn ti dajọ ẹwọn gbere fun lorileede United Arab Emirates lori ẹsun fifowo ṣatilẹyin fawọn afẹmiṣofo Boko Haram.

Igbimọ tijọba gbe kalẹ yii ti ṣewadii, aṣiri si ti tu si wọn lọwọ pe olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu, atawọn ẹmẹwa ẹ n ri awọn eeyan ṣofofo fun un nipa ohun to n lọ nile ati lẹyin odi, bẹẹ lawọn olowo bii ṣẹkẹrẹ kan fori pamọ, awọn ni wọn n ṣatilẹyin fun ọkunrin naa ati ẹgbẹ rẹ, awọn kan si tun wa lẹyin odi, niluu oyinbo ti wọn n fowo sọwọ si wọn.

Bakan naa ni igbimọ yii ti ri i pe o kere tan, ẹnikan wa nileegbimọ aṣofin wa, ọkan lara awọn aṣofin ni, oun lo n fowo ki ọkẹrẹ Sunday Igboho laya, to fi n ṣekun gbẹndu sọlọdẹ.

Malami tun sọ pe awọn orileede kan wa ti wọn mọ si ina ijijangbara to n ru tuu lorileede yii, o lawọn orileede ọhun fẹ ki Naijiria fọ si wẹwẹ. O ṣekilọ pe kawọn orileede naa tete yaa lọ jawọ ninu erongba ati igbesẹ wọn, o ni ki wọn so ewe agbejẹẹ mọ’wọ ti wọn o ba fẹẹ ri pipọn oju ijọba apapọ.

Leave a Reply