Ẹgbẹ Afẹnifẹre taku: Afi ka jokoo lati jiroro lori ibagbepọ wa bii orileede

Faith Adebọla, Eko

Ẹgbẹ to n ja fun iṣọkan ọmọ Yoruba, Afẹnifẹre, ti sọ pe inu inira gidi lorileede Naijiria wa lasiko yii, ko si sọna mi-in ta a fi le yanju iṣoro orileede yii ju ka jokoo yi tabili po, ka jiroro boya ki kaluku ṣe tiẹ lọtọọtọ ni tabi ka ṣi wa papọ lodidi.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lẹyin ipade wọn to waye nile Aṣaaju ẹgbẹ naa, Oloye Ayọ Adebanjọ, nipinlẹ Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni wọn ti sọrọ ọhun.

Atẹjade ọhun ka lapa kan pe:

“Ẹgbẹ Afẹnifẹre ti fara balẹ ṣagbeyẹwo iṣoro eto oṣelu to n mi orileede wa jigijigi, gbogbo wa la si gba pe wahala yii iba ma ṣẹlẹ ka ni iwe ofin akọkọ tawọn aṣaaju wa laye akọkọ fun wa la ṣi n lo ni.

Lemọlemọ la n pariwo pe iwe ofin tawọn ijọba ologun gbe kalẹ yii ko le ṣiṣẹ, idi si niyẹn tẹgbẹ Afẹnifẹre fi kopa ninu eto ọṣelu 1999 nipasẹ ẹgbẹ oṣelu AD (Alliance for Democracy), tori a fẹ kilẹ Yoruba da duro gedegbe lagbo oṣelu ni.

Tori ẹ naa la si ṣe pariwo ipade apero Sovereign National Conference lasiko ijọba Goodluck Jonathan. Wọn ṣeto apero loootọ lasiko yẹn, sibẹ, ijọba o tẹle awọn aba tawọn eeyan fẹnu ko le lori lapero ọhun titi doni.

Idi ree ti a fi fẹnuko bayii pe dandan ni ka jokoo yi tabili po, ka si jọ jiroro, ka jọ da a ro sọtun-un sosi, boya a ṣi le wa papọ bii orileede kan tabi ki kaluku gba ilẹ rẹ lọ, ka pin.

Aba meji ni Afẹnifẹre ni lori ọrọ yii, akọkọ ni ka pada si iwe ofin ọdun 1963 ọjọun, eyi tijọba ologun wọgi le.

Ta o ba si ṣe iyẹn, ka pe ipade awọn agbaagba ati aṣoju ẹya kọọkan lorileede yii, ati awọn tọrọ kan, ipade naa la ti maa jiroro awọn ohun ti ẹya kọọkan fẹ, ati bi ajọṣe wa yoo ti ri. A gbagbọ pe eyikeyii ninu aba meji yii lo le yanju iṣoro orileede yii.

A gbọdọ ṣiṣẹ lori ọrọ yii, ka wa iyanju siṣoro wa ṣaaju eto idibo ọdun 2023, tori iṣoro Naijiria ko ni i kasẹ nilẹ lai ka ẹgbẹ yoowu to jawe olubori lọdun naa si, o maa maa pọ si i ni ta o ba tete ṣe nnkan si i bayii.

Afẹnifẹre gbagbọ ninu pe ka wa niṣọkan, ṣugbọn iṣọkan to maa maa rẹ ilẹ Yoruba jẹ kọ, lọdọ tiwa, ile la ti n ko ẹṣọ r’ode ni.”

Lara awọn eeyan pataki ọmọ ẹgbẹ ọhun to pesẹ sibi ipade naa ni: Igbakeji olori ẹgbẹ, Ọba Ọladipọ Ọlaitan; Igbakeji Akọwe ẹgbẹ wọn, Ọgbẹni Leke Mabinuori, Gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ ri, Dokita Oluṣẹgun Mimiko; Oloye Cornelius Adebayọ, Oloye Ṣupọ Ṣonibarẹ, Abagun Kọle Ọmọlolu, Sẹnetọ Kofoworọla Bucknor-Akerele, Sẹnetọ Gbenga Kaka, Oloye Dayọ Duyile, Dokita Yọmi Atte, Ọjọgbọn Ọpẹyẹmi Agbaje, ati Ọgbẹni Jare Ajayi.

Leave a Reply