Faith Adebọla, Eko
Ijọba Eko ti ṣalaye pe loootọ lawọn fẹ ki gbigba abẹrẹ ajẹsara arun Korona kale-kako fun tẹru-tọmọ nipinlẹ Eko, ṣugbọn kidaa awọn to ba lọọ gba abẹrẹ ọhun lawọn ojuko tijọba ṣeto rẹ ni wọn maa gba a lọfẹẹ, ẹgbẹrun mẹfa naira (N6,000) lawọn to ba fẹẹ gba a lọsibitu aladaani maa san.
Atẹjade kan, eyi ti Akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Akoṣile, buwọ lu l’Ọjọbọ, Tọsidee, lorukọ Gomina Babajide Sanwo-Olu lori ọrọ abẹrẹ ajẹsara Korona lo tanmọlẹ sọrọ yii.
Sanwo-Olu ni tori kawọn eeyan pupọ le gba abẹrẹ ajẹsara naa lawọn ṣe ṣeto pe ki abẹrẹ ọhun wa nikaawọ awọn ileewosan aladaani meloo kan. O lawọn araalu kan le wa ti wọn o ni i nifẹẹ lati gba abẹrẹ ọhun ni gbangba walia tawọn ero pọ si, wọn maa fẹ ki adagba tabi ileewosan aladaani.
O lawọn eeyan bẹẹ maa ni lati san ẹgbẹrun mẹfa ọhun lati kaju awọn inawo pẹẹpẹẹpẹ lori abẹrẹ naa, o si ṣalaye pe awọn o gba owo abẹrẹ ajẹsara Korona o, bẹẹ lawọn o ta abẹrẹ naa fawọn eeyan rara.
O ni kiki awọn ọsibitu ati ibudo tijọba fọwọ si nikan lawọn maa gbe abẹrẹ ajẹsara naa lọ, o si ṣekilọ gidigidi fawọn to ba n gbero lati ṣe ayederu ibudo tabi abẹrẹ ajẹsara ọhun lati maa fi lu jibiti, pe ki wọn ma dan an wo, tori kele ofin maa gbe wọn.
Bakan naa, Sanwo-Olu ni kawọn eeyan wa lojufo, paapaa lasiko pọpọ-ṣinṣin ipari ọdun to wọle de tan yii, o lawọn alejo maa wọlu latilẹ okeere, wọn maa waa ba awọn ọrẹ ati mọlẹbi wọn ṣọdun, iyẹn si le fa ewu arankanlẹ arun Korona lẹẹkẹrin.
O ni kawọn eeyan ma ṣe tura silẹ lori titẹle awọn alakalẹ ofin ati eewọ arun naa, titi kan ikorajọ rẹpẹtẹ, lilo ibomu ati sanitaisa ni gbogbo igba.
O ni ti nnkan ba lọ bo ṣe yẹ, awọn nireti pe iye olugbe Eko to maa ti gba abẹrẹ naa lopin ọdun 2021 yii yoo ti to miliọnu mẹrin.