Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Laaago mẹfa aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa yii, ni ijamba kan ṣẹlẹ ni Lenuwa, lagbegbe Makun Tuntun, iyẹn loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, ẹsẹkẹsẹ lawọn baale ile meji doloogbe, nigba ti tanka kọ lu bọọsi akero tawọn ọkunrin naa wa ninu ẹ, to si pa meji ninu wọn.
Ohun ti a gbọ ni pe bireeki ọkọ tanka ti nọmba ẹ jẹ AKD 549 XL lo daṣẹ silẹ, ọkọ naa si bẹrẹ si i ṣe radarada laarin ọna, titi to fi lọọ kọ lu bọọsi akero ti nọmba tiẹ jẹ KSF 259 CQ.
Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi ti i ṣe Alukoro TRACE, ṣalaye pe awọn ọkunrin mẹrin ni ijamba yii kan, o ni meji ku ninu wọn latari ikọlu ọhun, awọn meji yooku si fara pa.
Mọṣuari to wa ninu ọsibitu Idẹra, ni Ṣagamu, lo ni awọn ko oku awọn meji to ṣalaisi lọ, ẹka itọju alaisan ni wọn si ko awọn meji to fara pa si nileewosan kan naa.
Nipa awakọ to wa tanka to paayan meji yii, Akinbiyi sọ pe ẹsẹkẹsẹ lo ti na papa bora, ẹnikẹni ko ri i.
TRACE ba ẹbi awọn to ṣalaisi kẹdun, wọn si rọ awọn awakọ nla nla yii pe ki wọn maa ṣọ ijanu ọkọ wọn daadaa ki wọn too bọ soju popo.
Wọn ni ki wọn ṣọra fun ere asapajude ati iwakiwa, bẹẹ ni ikilọ naa ko yọ gbogbo awakọ silẹ pẹlu.