Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti tẹ ọmọdekunrin kan, ẹni ti wọn forukọ bo laṣiri, odidi baagi igbo (Indian hemp) ni wọn ka mọ ọn lọwọ.
Agbegbe Sabo, niluu Oṣogbo, la gbọ pe wọn ti ri ọmọkunrin naa mu. Gẹgẹ bi ọkunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, Ọlatoye, ṣe sọ, ọpọlọpọ wakati ni wọn fi dọdẹẹ rẹ ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.
Ọlatoye sọ siwaju pe ọkan pataki lara awọn to n tagbo niluu Oṣogbo ni afurasi naa n ṣiṣẹ fun, koda, o tun pe ọga rẹ ọhun lori foonu lọgan ti ọwọ awọn Amọtẹkun tẹ ẹ lati wa gba a silẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alakooso ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, sọ pe lẹyin ti awọn mu un ni awọn fa a le awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun iwadii.
Amitolu ṣalaye pe aadọta kilogiraamu igbo ni awọn ba ninu baagi to gbe lọwọ, awọn si ti n wa ẹni to n ṣiṣẹ fun gan-an bayii. O ni afurasi ọhun pe ọga rẹ pe ko waa gba oun silẹ, ṣugbọn ọga rẹ ko ti i yọju.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ko ni i dẹkun didẹ pampẹ mu awọn ọdaran ti wọn ba ro pe awọn le sọ ipinlẹ Ọṣun di ibuba, afi ti wọn ba kuro tabi ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.