Ọwọ tẹ awọn Fulani pẹlu ẹẹdẹgbẹta ibọn, ọpọlọpọ ida ti wọn ti rẹ loogun  atawọn ohun ija oloro mi-in l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Inu ibẹru bojo lawọn eeyan ipinlẹ Ondo wa lọwọlọwọ latari awọn ọmọ Fulani kan tọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ laarin oru ọjọ Ọjọbọ, Tọsidee, si ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Ninu alaye ti Alakooso agba fun ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ṣe fawọn oniroyin nigba to n ṣafihan awọn ọdaran Fulani ọhun lọfiisi wọn to wa niluu Akurẹ lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, o ni awọn eeyan kan lo ta awọn lolobo lori irin ifura awọn Fulani ọhun ti awọn fi lọọ dena de wọn loju ọna marosẹ Akurẹ si Ondo ni nnkan bii aago kan aabọ oru.

O ni ko pẹ rara tawọn ọlọpaa atawọn ẹsọ Amọtẹkun fi n duro de wọn nigba ti wọn ko ara wọn de ninu ọkọ Toyota Hummer bọọsi mẹta.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, Oloye Adelẹyẹ ni ṣe lawọn awakọ mẹtẹẹta ọhun kọ lati duro nigba tawọn ẹṣọ alaabo da wọn duro l’Akurẹ, gbogbo igi ti wọn ko di oju ọna ni wọn mu gun ti wọn si ṣe bẹẹ sa lọ mọ awọn to fẹẹ mu wọn lọwọ.

Aarin oru naa ni wọn ti sare kan sawọn ẹṣọ alaabo mi-in to wa loju ọna marosẹ Ọwẹna, loju ọna Ondo, ohun ti wọn ṣe l’Akurẹ naa ni wọn tun ṣe fun wọn, koda, ori lo ko awọn ọlọpaa to dabuu ọna de wọn yọ pẹlu bi wọn ṣe gbiyanju lati fi ọkọ kọ lu wọn níbi tí wọn ti n sa asala.

Bayii ni wọn ṣe titi wọn fi raaye wọ ilu Ondo, nibi tawọn ọlọpaa atawọn ẹsọ Amọtẹkun ti gẹgun de wọn, ti wọn si fipa da wọn duro, sibẹ, meji ninu awọn ọkọ bọọsi naa si raaye sa lọ nigba ti wọn ri ọkan yooku mu mọlẹ.

Awọn Fulani mejidinlogun ni wọn ba ninu bọọsi tọwọ tẹ pẹlu awọn apo idọhọ meji ti wọn di awọn nnkan bii ẹpa sì ninu.

Iyalẹnu lo jẹ fawọn ẹṣọ alaabo funra wọn nigba ti wọn tu awọn apo ọhun tan ti wọn si ba awọn nnkan ija oloro bii ọbẹ asooro loriṣiiriṣii, ida loriṣiiriṣii, ọpọlọpọ ọkọ, ibọn ati ọta ibọn.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun wọn ni wọn ti jẹwọ pe ipinlẹ Katsina lawọn ti wa, wọn ni ẹnikan lo ko awọn nnkan ija naa fawọn, to si ni kawọn maa bọ niluu Akurẹ.

Ẹni ti wọn kọ lati darukọ ọhun ni wọn lo sọ fawọn pe kawọn maa bọ l’Akurẹ na, ati pe oun yoo maa sọ iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe fun wọn lẹyin igba ti wọn ba ti gunlẹ s’Akurẹ.

Asiko ti wọn n ṣafihan awọn ọdaran naa ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ẹsọ Amọtẹkun n sọ fun wa pe awọn Fulani ọhun jẹwọ fawọn lẹyin tọwọ tẹ wọn pe gbogbo ọbẹ ati ida ti awọn ko dani ni wọn ti rẹ pẹlu majele.

O ni wọn kilọ fawọn pe kawọn kiyesara nitori pe eyikeyii ninu awọn ọbẹ, ada ati ida naa ko gbọdọ kan ẹjẹ ẹnikẹni, wọn ni ọrun lẹrọ feni to ba ti kan ẹjẹ rẹ.

Ọsẹ to kọja yii lọwọ awọn Amọtẹkun kọkọ tẹ awọn Fulani mejidinlogun kan lagbegbe Arakalẹ, niluu Akurẹ, awọn tọwọ tẹ ọhun ni wọn fa le ṣeriki awọn Hausa ipinlẹ Ondo lọwọ nigba naa pe ko tete da wọn pada si ipinlẹ koowa wọn.

Lara ohun ti wọn lawọn eeyan ọhun sọ nigba ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọfiisi awọn Amọtẹkun ni pe awọn bii ọgbọn ni wọn ti kọkọ gunlẹ siluu Akurẹ ṣaaju awọn.

Awọn wọnyi lawọn ẹṣọ alaabo ṣi n wa lọnakọna kọwọ too tun tẹ awọn mejidinlogun mi-in pẹlu ọpọlọpọ nnkan ija oloro.

Ninu ọrọ rẹ, Oloye Adelẹyẹ ni loootọ lo wa ninu ofin orilẹ-ede Naijiria pe ẹnikẹni lo lẹtọọ lati lọ sibikibi nigba to ba wu u, ṣugbọn ki lo de to jẹ asiko yii gan-an lawọn Fulani atawọn ọmọ Hausa sọ ara wọn di adimẹru ti wọn si n ya wọ ipinlẹ Ondo tọsan toru.

O ni ko si eyi to kan ẹsọ Amọtẹkun nípa ẹya tabi awọn eeyan ti awọn n fi pampẹ ofin gbe nitori pe alaafia ipinlẹ Ondo lo jẹ oun logun ju ariwo lasan tawọn eeyan n pa kiri lọ.

 

 

Leave a Reply