Faith Adebọla, Eko
Niṣe lobinrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Abilekọ Dorcas Ali, yari kanlẹ ni kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Igando, lọjọ Aje, Mọnde yii, pe ki wọn ṣaa ba oun tu igbeyawo ọdun mẹrindinlogun to wa laarin oun ati ọkọ rẹ, Wọle Ali, ka, o loun o ṣe mọ.
Obinrin to fẹẹ jawee ikọsilẹ fun ọkọ rẹ naa ṣalaye nile-ẹjọ pe ọpọ igba loun ti ka ọkọ oun mọ ori awọn obinrin to n yan lale nihooho goloto ti wọn n laṣepọ, o ni ki i ṣe obinrin kan o, oriṣiiriṣii lo maa n gbe, o lo maa n ṣọ koun jade lọ si iṣọ oru tawọn maa n ṣe ni ṣọọṣi ni.
O tun lọkọ oun ti sọ oun di ẹgusi baara, alubami lo maa n lu oun nigbakuugba ti ede-aiyede ba ti waye laarin awọn, o lọpọ igba lo ti lu oun daku, to jẹ ọsibitu lo gba oun silẹ, toun si fara pa yanna yanna. Iyaale ile yii ni ọjọ kan wa to fibinu da kẹrosinni soun lara, to fẹẹ sun oun looyẹ, kawọn eeyan too gba oun silẹ lọwọ ẹ.
Olupẹjọ naa tun fẹsun kan ọkọ ẹ pe niṣe lo fẹẹ dọgbọn jogun ile toun kọ, tori ẹ lo ṣe n wa gbogbo ọna lati gbẹmi oun, oun si ti pinnu lati pin gaari pẹlu rẹ.
Nigba ti mo fẹẹ ra ilẹ, mo mu un dani tori mi o mọwe, orukọ mi nikan ni wọn si kọ sori risiiti ti mo fi ra ilẹ nigba yẹn. Ṣugbọn laipẹ yii ti mo maa ri risiiti naa, mo ri i pe ọkọ mi ti lọọ kọ orukọ meji sori ẹ, o ti lọọ gbẹyin fi orukọ ara ẹ kun un, o fẹẹ jogun mi lai ku mi.”
Obinrin naa tun fẹsun kan ọkọ ẹ pe o maa n fi ibalopọ du oun, eyi si ni ko jẹ koun ti bimọ fun un latigba tawọn ti fẹra. O ni niṣe lo maa n ti oun kuro lẹgbẹẹ ẹ toun ba sọ fun un pe kawọn ṣere ifẹ, o si ti ju ọdun mẹfa lọ to ti gori oun, o lọkunrin naa ti bimọ sita, o si lawọn ale kaakiri.
Bakan naa lo tun fẹsun kan ọkọ rẹ ọhun pe oun ba a ya ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (N300,000)lati fi ra mọto, ṣugbọn ẹgbẹrun lọna aadọta pere lo san pada ninu owo naa, niṣe lo fowo ọhun da gbese soun lọrun, ko si bikita lati san an mọ, kaka bẹẹ, o maa n ji oun lowo to ba ti le foju kan pọọsi owo oun ni.
“Mi o nifẹẹ ẹ mọ rara o, ẹ sọ fun un ko kẹru ẹ jade nile mi, ko jẹ ki n wa lalaafia ara mi o”, obinrin naa lo sọ bẹẹ ni kootu.
Nigba tọrọ kan ọkọ rẹ lati ro arojare, baba ẹni ọdun mọkandinlọgọta naa to n ṣiṣẹ dẹrẹba sọ pe irọ niyawo oun n pa, o loun ko ṣiwọ soke lu u lẹẹkan ri, ati pe oun loun ni ile ti iyawo naa n sọrọ rẹ yii, o ni ko si ṣile kan Dorcas nibẹ.
“Oloogun bii Ẹgbẹji ni baba iyawo mi, oun lo wa nidii iṣoro wa, atigba ti mo ti fẹ ọmọ ẹ lo ti n gbogun ti mi. Baba iyawo mi diidi fẹẹ baye mi jẹ ni, ati oju oorun ati oju aye lo fi n ba mi ja, oun lo si jẹ ki okoowo mi dojuru,” Wọle lo n ṣalaye bẹẹ.
Ọkunrin naa jẹwọ pe loootọ niyawo oun ba oun ya ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira, ṣugbọn oun ti san gbogbo owo naa pada pẹlu ele ori ẹ fun un.
O loun o fẹẹ kọ ọ silẹ, yatọ si ti baba ẹ to n gbogun ti oun yii, o ni oun ṣi nifẹẹ iyawo naa.
Ṣa, Adajọ Adeniyi Kọlawọle ti paṣẹ pe ki tọkọ-taya naa pada sile, ki wọn jẹ kawọn mọlẹbi wọn ba wọn da sọrọ naa, ki wọn feegun otolo to o, ki wọn si pada waa jabọ fun kootu lẹyin oṣu kan, ki ile-ẹjọ le pinnu ibi ti wọn maa gbe ọrọ wọn ka.