Faith Adebọla, Eko
Ilumọ-ọn-ka ajihinrere agbaye ati olori ṣọọṣi Ridiimu lapapọ (Redeemed Christian Church of God), Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, ti ṣekilọ fawọn oloṣelu to n sare soke sodo latari pe wọn fẹẹ rọwọ mu ninu eto idibo 2023 pe ki wọn simẹdọ na, tori ko sẹni to le fọwọ sọya nipa ọjọ iwaju orileede yii, boya Naijiria ṣi maa wa ki eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 too waye, ati boya eto idibo naa yoo tiẹ waye tabi ko ni i waye.
Nibi eto idupẹ oloṣooṣu ti ijọ rẹ maa n ṣe lo ti sọrọ yii, nigba ti eto toṣu kọkanla yii n waye lọjọ Aiku, Sannde, opin ọsẹ to kọja yii.
Adeboye ni ọrọ bawọn oloṣelu kan yoo ṣe depo aarẹ orileede yii to mumu laya wọn lasiko yii lewu, tori ko sẹni to mọ ọla, ko sẹni to le sọ boya Naijiria ti wọn fẹẹ ṣakoso yoo ṣi wa, tabi boya eto idibo naa yoo waye, Ọlọrun nikan lo mọ, Oun lo le sọ.
“Ọdun 2021 la ṣi wa yii, awọn kan si ti fẹẹ pa ara wọn tori eto idibo 2023. Wọn o tiẹ mọ boya 2023 maa de, wọn o mọ boya awọn gan-an ṣi maa wa laaye di ọdun 2023 ọhun, ko sẹni to le fọwọ sọya pe oun maa wa laaye di ọla, Ọlọrun nikan lo mọ ẹni ti oju ẹ maa ri ọdun 2023.
Ẹnikan lo n bi mi leere pe ‘ta lemi ro pe o maa di aarẹ lọdun 2023,’ mo ni ‘aarẹ ibo?’, o ni ‘ti Naijiria yii,’ mo ni bawo lo ṣe da oun gan-an loju pe Naijiria funra ẹ maa wa di ọdun 2023, ṣe o le bura si i.
Ajihinrere naa gba awọn ọmọ ijọ ẹ lamọran lati maa huwa mimọ, ki wọn le wọ ijọba ọrun, bẹẹ lo si ṣadura ki Ọlọrun rọ mọlẹbi awọn to padanu eeyan wọn ninu ile alaja mọkanlelogun to wo lagbegbe Ikoyi lọsẹ to kọja, lọkan, ko si bu ororo itura si ọgbẹ ọkan wọn.