Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, fun Onipokia tilu Ipokia, nijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun, Ọba Adeṣọla Ọlaniyan, lọpa aṣẹ gẹgẹ bii ọba kọkandinlaaadọta ti yoo jẹ niluu naa.
Kọmiṣanna fun ijọba ibilẹ ati ọrọ lọbalọba nipinlẹ Ogun, Họnarebu Afọlabi Afuwapẹ, to ṣoju gomina nibi ayẹyẹ naa to waye nile ọlọmọọba Iwaye Dodo, niluu naa, lo gbe ọpa aṣẹ fun ọba tuntun yii.
Bẹẹ nijọba rọ Ọba Ọlaniyan lati lo ipo ọhun fun ilọsiwaju ilu yii.
Tilu tifọn lawọn araalu naa fi ki kabiyesi kaabọ saafin.
Ninu ọrọ rẹ lẹyin ti wọn fun un lọpa aṣẹ, Ọba Ọlaniyan beere fun atilẹyin gbogbo awọn ọmọ ilu naa. Kabiyesi ni ko si ẹni to le de ipo ọba bi ki i ba ṣe pe Ọlọrun lọwọ si i. O waa ṣeleri pe gbogbo ohun ti yoo mu ilọsiwaju ati iṣọkan ba ilu Ipokia loun yoo maa ṣe.