Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Abuku ki i kan ẹni ti ko jẹ nnkan, eeyan pataki labuku maa n wa ka. Afi keeyan maa ṣọ iwa rẹ laarin awujọ, ko ma huwa ti abuku yoo kan an, ko si ma rin ni bebe rẹ rara. Ni gbogbo ọsẹ to kọja yii, koda titi dasiko yii ni iroyin abuku to kan ọga awọn onifuji nni, Alaaji Wasiu Ayinde Marshal ( K 1), ṣi n ja ran-in lori ayelujura.
Niṣe ni wọn ni K1 gbowo lọwọ awọn eeyan to pe e sode ere, ko si lọọ ṣere ọhun fun wọn. Koda, wọn ni Emmanuella Rọpo, ọmọbinrin ti Wasiu ṣẹṣe n fẹ bayii lo fowo to gba lode ere kọle fun. Wọn ni ninu owo ọhun lo fẹẹ fi ṣegbeyawo alarinrin pẹlu iyawo tuntun yii lọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, niluu Abẹokuta.
Bẹẹ loko ọrọ n bọ lọtun-un losi lori Fesibuuku ati Instagraamu, ti wọn n pe Oluaye awọn onifuji lorukọ buruku, wọn ni ẹlẹtẹ eeyan kan bayii ni Mayegun, ki i ṣe ẹni apọnle rara.
Ẹka irorin ayelujara kan ti wọn n pe ni ‘Gistlovers’, royin pe Wasiu Ayinde dojuti awọn to pe e lode pe ko waa ṣere, nigba to kọ ti ko yọju sode wọn debi ti yoo tilẹ kọrin nibẹ.
Ẹka iroyin naa sọ pe bi K1 ko si ṣe lọ sode naa ni ko tun da owo awọn to pe e sode naa pada fun wọn, awọn iyẹn si beere owo wọn titi, niṣe ni Oluaye ko da wọn lohun.
Ọkan ninu awọn ti wọn ni wọn pe K1 pe ko waa ṣere ti ọkunrin naa ko si lọ ni wọn pe orukọ ẹ ni Lanre Ọlakanlu, iyẹn ọkunrin tawọn eeyan tun mọ si Mista Kogberegbe.
Ẹka iroyin Gistlovers yii gbe ọrọ ti wọn ni Wasiu Ayinde ati ọkunrin naa jọ sọ sira wọn jade loju opo Fesibuuku, nibẹ ni Ọgbẹni Ọlakanlu ti sọ pe gbogbo owo ti Wasiu loun fẹẹ gba loun san fun un, ko si waa ṣere foun, n lọkunrin naa ba kọ ọ sibẹ pe Ade ori ọkin yoo too di ade ori ti wọn fi n wọlẹ laipẹ.
O ni ti Wasiu ba ro pe oun tobi, oun si le maa fi awọn eeyan yooku wọlẹ, irọ lo pa.
Ọlakanlu sọ pe Mayegun sare lọọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn ẹka iroyin elebi kan, ki wọn le maa ba a bo aṣiri irọ to n pa kiri.
O ni ki K1 sanwo ere to gba lọwọ awọn eeyan pada. O ni awọn eeyan meji kan wa ti wọn n sunkun soun lọrun bayii, nitori Wasiu gbowo lọwọ wọn, ko lọọ kọrin fun wọn, ko si tun da owo wọn pada.
Ọkunrin yii sọ pe ki Mayegun da owo awọn to jẹ lowo pada, abi ṣe iyẹn tun ṣoro lati ṣe fun un ni.
Nibi to ti waa fọ gbogbo ẹ loju ni ibi to ti kọ ọ pe, ‘nigba ti ọrọ yii ba le tan, Ọgagun Wasiu oloko dogi-dọpẹ, afoko ṣaanu, o o ni i laiki ẹ o. Mo maa fun gbogbo awọn to o jẹ lowo ladirẹsi ibi ti iwọ ati Emmanuella ti fẹẹ ṣegbeyawo lọjọ kejidinlogun, o o ni i fẹ kirU ẹ ṣẹlẹ.”
Awọn ọrọ mi-in ti ko tiẹ ṣee kọ soju iwe iroyin tun wa ninu ohun ti ọkunrin yii sọ si Wasiu Ayinde, to ni Mayegun naa ki i ṣe ẹni apọnle rara. Bi ọrọ ṣe n bọ sori Wasiu lo n bọ sori iyawo ọsingin to ṣẹṣẹ fẹẹ gbe naa, ti epe diẹdiẹ si tun n kun un pẹlu.
Bẹẹ lọsẹ to kọja yii ni Emmanuella kọ ọrọ iwuri nipa Wasiu Ayinde sori ayelujara, to ni iru ọkunrin bii tiẹ ṣọwọn.
Rọpo pọn Oluaye le pupọ, o lọtọ lohun toun ti n ro nipa rẹ tẹlẹ, aṣe isunmọni la a mọṣe ẹni, oun ṣẹṣẹ gba pe ọtọ ni tiyọ laarin eroja ọbẹ ni nigba toun sun mọ Mayegun. Afi bo ṣe waa jẹ pe lẹyin apọnle naa ni abuku bẹrẹ si i jẹ yọ fun ọkunrin naa.
Ẹlomi-in to tun fẹsun yii kan Oluaye Fuji ni ọkunrin adẹrin-in-poṣonu ti wọn n pe ni Ẹlẹnu, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Babatunde Akinlami.
Ori ẹka Instagraamu ni Ẹlẹnu ti kọkọ kede ẹ pe oun sanwo ere fun Wasiu Ayinde loṣu kẹsan-an ọdun yii lati waa ṣere foun, o ni titi dasiko yii, ọkunrin onifuji naa ko waa ṣere ọhun, bẹẹ ni ko dawo oun pada.
Ẹlẹnu pe Wasiu ati maneja ẹ, Mike Fash, o ni ki wọn ṣe nọma.
Koda, orilẹ-ede Amẹrika lo yẹ ki ere ti Ẹlẹnu pe wọn si yii ti waye, oun si ro pe ki wọn waa ṣere naa nirọrun gẹgẹ bi wọn ṣe ṣeleri ẹ foun ni, ṣugbọn nigba ti Ẹlẹnu ko ri Wasiu atawọn elegbe ẹ, ti wọn ko tun da owo rẹ pada fun un, ọkunrin alawada naa gba ori ẹka Instagraamu lọ, o si kọ ọrọ sibẹ pe ẹni apọnle ni Wasiu Ayinde lọwọ oun lọjọ to ti pẹ, bẹẹ naa loun si ṣe fẹran ere rẹ. O ni ṣugbọn eyi ti wọn n ṣe yii ko daa rara, wọn si gbọdọ dẹkun ẹ.
Ẹlẹnu sọ fun Wasiu loju opo naa pe owo dọla rẹpẹtẹ loun san fun un, maneja rẹ si n sọ foun pe nitori Korona to wa nita, gbogbo elegbe gbọdọ gba abẹrẹ ki wọn too wa lo fa a tawọn ko ṣe ti i wa, nigba to ya ni wọn tun bẹrẹ si i purọ mọ fisa, ti wọn ni ai ti i riwee irinna gba lo fa a tawọn ko fi wa.
Ẹlẹnu ni ki wọn ma wulẹ da ara wọn laamu mọ, oun paapaa ko tiẹ ṣe mọ, ki wọn da owo oun pada, ki wọn mọ bi wọn yoo ṣe ta ayẹyẹ toun tori ẹ sanwo fun wọn fẹlomi-in, ki wọn kowo toun foun ni, oun ko ṣe mọ.
Bi ti Ẹlẹnu yii ṣe tun jade lawọn eeyan bẹrẹ si i sọrọ nipa ohun to n ṣẹlẹ si Mayegun ilẹ Yoruba yii, wọn ni Wasiu to jẹ ahun buruku loun funra ẹ, ti ki i lee fun eeyan lowo, oun lo waa n gbowo lọwọ awọn ololufẹ rẹ ti ko si lọọ ṣere fun wọn bayii, to si fẹẹ sọ ara rẹ di ẹni abuku, to fẹẹ sọ Ade ori ọkin rẹ di ti ẹyẹ buruku, ẹyẹkẹyẹ.
Nigba ti ọrọ naa ko yee tan kaye, Mayegun naa jade sọrọ loju opo Instagraamu rẹ, o loun ko fagi le irin-ajo ilu oyinbo kankan lẹyin toun gbowo lọwọ wọn, gbogbo eto loun si ti ṣe kalẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oun lati rin irin naa, Fisa nikan lo ku ti ko ti i pari, eyi ko si ki i ṣe iṣẹ oun, bi ko ṣe ti Ẹmbasi Amẹrika to wa nilẹ yii.
K1 sọ pe oun ko tilẹ fẹẹ fesi si ọrọ ọhun tẹlẹ, ṣugbọn nitori awọn ololufẹ oun toun bọwọ fun pupọ, to si yẹ koun ṣalaye ọrọ fun lo fa eyi toun n ṣe yii.
O loun ko ni i pẹlu ọbọ awọn ti ko mọ bi wọn ṣe n lo ayelujara jawura, ki kaluku kọ beeyan ṣe n sọrọ loju opo yii, ki wọn yee lo ede to le tabuku ẹni keji wọn.
Ṣa, awuyewuye ọhun ko ti i duro.Boya bawọn ti wọn n fẹsun kan Wasiu ba ri owo wọn gba, tabi to ba ṣere ọhun fun wọn, gbogbo ẹ yoo yanju lọjọ kan.