Faith Adebọla, Eko
“Mi o ni i fakoko ṣofo mọ lori ọrọ bi Buhari ṣe n ṣojuṣaaju lori ẹya ati ẹsin lorileede yii mọ, ko sẹni to tun nilo alaye rẹpẹtẹ lori iyẹn, ohun ti gbogbo aye ti mọ ni, iwa ẹlẹyamẹya rẹ, ati ẹlẹsinmẹsin rẹ ko fara sin rara, oun naa o si fi pamọ, ṣugbọn asiko ti to bayii lati jẹ ki gbogbo aye mọ ipinnu tiwa.
Gbogbo ipá ati agbara to wa lọwọ wa la maa sa lati fi ba awọn eeyan wa sọrọ, ta a si maa yi wọn lọkan pada lati ma ṣe nigbagbọ tabi ṣatilẹyin fun eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 to n bọ yii, tori irọ ati jibiti leto naa yoo jẹ bi ko ba si alaafia ati aabo nilẹ wa. Ko si le si alaafia ati aabo bi atunto gidi ko ba kọkọ waye na, ka si jọ ba ara wa sọrọ lori bi ajọṣepọ wa ni Naijiria ṣe maa jẹ.”
Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, lo sọrọ yii lasiko apero agbaye ti ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba naa ṣe pẹlu awọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun yii. Apero naa waye ninu gbọngan apero otẹẹli kan lagbegbe Ikoyi, l’Erekuṣu Eko.
Ọpọ awọn agbaagba ati olori ẹgbẹ naa l’Ekoo ati kaakiri awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba, bii Igbakeji gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ri, Abilekọ Kofoworọla Bucknor-Akerele, Ajagun-fẹyinti Muyiwa Okunnọwọ, Ọba Ọladiipọ Ọlaitan, Igbakeji Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọgbẹni Jare Ajayi, Alukoro apapọ, Ọgbẹni Ṣọla Ebiṣeeni, Akọwe ẹgbẹ, Ọmọọba Elias Matiminu, Baṣọrun Oluwaṣẹgun Sanni, Mọgaji Gboyega Adejumọ, Dokita Ẹbun Sonaya, Ọgbẹni Yẹmi Agbaje to jẹ olori ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, ati awọn eekan eekan mi-in.
Oloye Adebanjọ bẹrẹ ọrọ rẹ pẹlu alaye lori bi nnkan ṣe n fojoojumọ buru si i lorileede yii, paapaa lori eto aabo, eto iṣẹlu, ẹlẹyamẹya, igbọjẹgẹ ijọba, ẹtan ati ifiya jẹ alaiṣẹ.
O bẹnu atẹ lu ofin orileede wa tọdun 1999 ti a n lo lọwọlọwọ yii, o ni ayederu pọnbele ni, tori ki i ṣe agbarijọpọ awa ọmọ Naijiria la ṣe e, ijọba ologun Abdulsalam Abubakar atawọn ẹmẹwa rẹ ni wọn kọ ọ, ti wọn si gbe e le awọn oloṣelu lọwọ latọdun naa.
O ni Naijiria yii ti yatọ patapata si erongba awọn baba nla wa ti wọn so wa pọ, ẹkọ ko si le ṣoju mimu, nnkan o le fara rọ nibẹ, ayafi bi atunto ba kọkọ waye.
O rọ ijọba lati ṣeto ipade apero nla mi-in fun iṣọkan Naijiria, ki wọn mu awọn aṣoju ẹya, ẹsin, oṣelu ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ, lati fori kori lori ajọṣepọ to le mu igba ọtun wa ni Naijiria, aijẹ bẹẹ, o lawọn o ni i gba ki ẹtan ati aifararọ yii maa lọ bẹẹ kọja ọdun 2023.
Nigba ti ALAROYE beere ohun ti ẹgbẹ naa yoo ṣe bi atunto ko ba waye, ati boya wọn ti jẹ ki Buhari mọ iru atunto ti wọn n beere fun, Alagba Adebanjọ sọ pe ‘orukọ ti a oo sọ ọmọ ẹni, inu ẹni ni i gbe’ lọrọ ohun tawọn yoo ṣe ti ijọba ba taku, o ni to bi di asiko to yẹ, igbesẹ to yẹ yoo tẹle e.
O ni Buhari mọ ohun ti atunto jẹ, irọ ni pe ko mọ ọn, ọpọ igba lawọn si ti jẹ ki Aarẹ ati awọn gomina, titi kan awọn ileegbimọ aṣofin kaakiri ilẹ wa, mọ nipa ibeere yii.
O ni eto aabo orileede yii ko le sunwọn si i ti ko ba si ọlọpaa ipinlẹ ati atunto Naijiria.
Ni ti ọrọ oṣelu ọdun 2023, ẹgbẹ Afẹnifẹre lawọn o ṣatilẹyin fun ẹnikẹni, awọn o si ni i ṣatilẹyin fun ẹnikẹni, koda bi onitọhun ba ṣeleri pe oun yoo ṣeto atunto toun ba bọ si ipo aarẹ, tori ẹlẹtan ati alabosi lasan ni gbogbo wọn. O ni gbogbo ileri ti Buhari le ko too di Aarẹ, ati eyi ti Tinubu ṣe pe ẹgbẹ oṣelu APC yoo mojuto ọrọ atunto ati awọn nnkan to wa ninu iwe ofin wa ni wọn kuna lati mu ṣẹ, awọn o si ni i jẹ ki itakun kan fọ awọn l’epo lẹẹmeji.