Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Tiṣa kan ti wọn porukọ rẹ ni Ọmọtayọ Adanlawọ ti gba idajọ ẹwọn gbere lati ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ lẹyin to jẹbi ẹsun fifipa ba ọmọ ọdun mẹwaa lo pọ. Ile awọn obi ọmọdebinrin naa to wa niluu Iju, nijọba ibilẹ Akurẹ, ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ kẹrinlelogun, osu kẹjọ, ọdun 2018.
ALAROYE gbọ pe ṣe ni ọdaran ọhun lọọ ka ọmọbinrin yii mọle lọjọ naa, to si fipa ba a lo pọ lẹyin to ri i pe awọn obi rẹ ti lọ soko. Nigba to ṣe ọmọ ọlọmọ bo ṣe wu u tan lo kilọ fun un pe ko gbọdọ wi fẹnikeni ti ko ba fẹẹ fiku ṣe ifa jẹ.
Inu kan lo n yọ ọmọ naa lẹnu ti wọn fi sare gbe e lọ sile-iwosan fun itọju, ọṣibitu yii lawọn dokita ti sọ fun wọn pe inu to n run un ki i ṣoju lasan, wọn ni ayẹwo ti awọn ṣe fun un fidi rẹ mulẹ pe ẹni kan ti fipa ba a lo pọ.
Eyi gan-an lo ṣokunfa bi ọmọ ṣe ṣẹṣẹ waa jẹwọ fun awọn obi rẹ, to ṣalaye ohun ti ọkan ninu awọn ọmọ ijọ baba rẹ ọhun foju rẹ ri lọjọ to waa ka a mọle.
Loju ẹsẹ lọrọ ti de agọ ọlọpaa, lati ibẹ ni wọn si ti taari rẹ rẹ lọ sile-ẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an. Ohun t osi sọ o dero ẹwon niyi o.