Faith Adebọla
“Ọmọ Naijiria gidi ni mi, emi o dẹ ni i dakẹ nibi to ba ti yẹ ki n ke tantan, tori agba ti o kẹhun sọrọ yoo kẹtan sare. Awọn janduku agbebọn ti yi Naijiria po bayii, wọn ti saba ti wa, ti igbesẹ gidi lodi si wọn ko ba ṣẹlẹ, afaimọ ni wọn o ni i fẹyin orileede yii balẹ laipẹ.”
Ọgbẹni Samuel Ortom, Gomina ipinlẹ Benue, lo n ṣekilọ ọrọ yii funjọba Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ awọn akọlu tawọn janduku agbebọn ṣẹṣẹ ṣe laipẹ yii nipinlẹ ọhun, ti wọn si fẹmi eeyan mẹjọ ṣofo.
Ortom ni o ti ju ẹẹdẹgbẹjọ (1,700) eeyan tawọn agbebọn fẹmi wọn ṣofo nipinlẹ Benue lẹnu igba ti Aarẹ Buhari dori aleefa yii, iye awọn abogunde ti wọn n gba itọju lawọn kampu kaakiri ipinlẹ naa ti ju miliọnu kan aabọ lọ.
O lawọn eeyan yii o fẹẹ pada sibugbe wọn mọ, tori ibẹru awọn apanijaye ọhun, gbogbo okoowo ati iṣẹ oojọ wọn lo si ti parẹ.
“Ẹgbẹ oṣelu APC yii ti ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ patapata, ki i ṣe pe wọn ja wa kulẹ nikan, wọn o tiẹ mọ ọna abayọ si iṣoro aabo, ọrọ-aje, iṣẹ agbẹ ati iṣọkan to n koju orileede yii, agbara wọn o gbe e rara ni.”
O lawọn to yẹ ki wọn sọrọ, ṣugbọn ti wọn o sọrọ lasiko yii paapaa buru ju awọn ọdaran funra wọn lọ.
O lawọn alagbara kan nileeṣẹ Aarẹ o jẹ koun tun foju kan Aarẹ Buhari mọ, niṣe ni wọn n gbegi dina toun ba fẹẹ lọọ ba a sọrọ nipa iṣoro eto aabo to gbode yii, idi niyẹn toun kuku fi n ba awọn oniroyin sọrọ, tori ewu nla lo rọ dẹdẹ sori Naijiria.