Faith Adebọla, Eko
“Wọn fa aṣọ ya mọ mi lọrun, wọn fipa mu mi jokoo silẹẹlẹ, gbogbo ara mi lo n gbọn, igbaju igbamu ni wọn da bo mi, ti wọn n gbo mi jigijigi, wọn n gba mi lori. Nigba ti wọn fi akọsilẹ yii han mi, tori emi kọ ni mo kọ ọ, emi si kọ ni mo sọ ohun ti wọn kọ sibẹ, mo sọ fawọn ọlọpaa bẹẹ. Ṣugbọn wọn kigbe mọ mi pe ki n tọwọ bọwe kia, mo fipa buwọ luwe yẹn ni, Princess lo sọ gbogbo ohun ti wọn kọ sibẹ fun wọn.”
Pẹlu ẹkun ni gbajugbaja oṣere tiata ati adẹrin-in poṣonu nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa fi n ṣalaye ohun toju ẹ ri lasiko ti wọn fi mu un loṣu kẹrin, ọdun yii, nile ‘Madam Princess’ ti wọn si fẹsun biba ọmọde ṣeṣekuṣe kan an, ati igba ti wọn wọ ọ de teṣan ọlọpaa ni Panti, lagbegbe Yaba, ti wọn gba akọsilẹ ẹsun rẹ silẹ.
Bọkunrin naa ṣe n fi ankaṣifi ọwọ rẹ nu oju rẹ lẹẹmẹwaa, bẹẹ lo n ṣalaye niwaju Adajọ Oluwatoyin Taiwo, awọn lọọya, ati gbogbo ero to kun kootu tẹmutẹmu.
Lati oṣu keje, ọdun yii, ni Baba Ijẹṣa ti n jẹjọ lori ẹsun marun-un ọtọọtọ ti ijọba ipinlẹ Eko fi kan an, wọn lo fipa ba ọmọbinrin ọmọọdun mẹrinla kan ti wọn forukọ bo laṣiiri lo pọ, wọn lo ti kọkọ ba ọmọ naa laṣẹpọ nigba tọmọ ọhun wa lọmọ ọdun meje sẹyin ko too tun ṣe ṣeṣekuṣe pẹlu ẹ lọmọọdun mẹrinla tọwọ palaba ẹ sṣgi yii. Fifọwọ kan ọmọde lọna aitọ wa lara awọn ẹsun naa.
Latigba ti igbẹjọ ti bẹrẹ, awọn ẹlẹrii olujẹjọ ni wọn ti n jẹrii gbe awọn ẹsun ọhun lẹsẹ, ti wọn si n ṣalaye idi tile-ẹjọ fi gbọdọ fiya jẹ Baba Ijẹṣa. Abilekọ Damilọla Adekọya, ti wọn n pe ni “Madam Princess,” toun naa jẹ oṣere adẹrin-in-poṣonu, ti ṣalaye bọrọ ṣe jẹ, bakan naa ni ọmọbinrin tọrọ da le lori naa ti sọ tẹnu ẹ, iya ọmọbinrin ọhun ti wa si kootu, awọn ọtẹlẹmuyẹ aladaani ti wọn ṣewadii ijinlẹ lori iṣẹlẹ ọhun ti mu awọn fidio ati ohun ti wọn ka silẹ wa, wọn si ti yọju ni kootu.
Ọjọ Ẹti yii ni ẹjọ kan Baba Ijẹṣa. Awọn agbẹjọro olupẹjọ si bẹrẹ si i bi i lere pe ko ṣalaye lori awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ ati akọsilẹ toun funra ẹ buwọ lu pe loootọ loun ṣaṣemaṣe ti wọn fẹsun rẹ kan an naa.
Baba Ijẹṣa ṣalaye pe oun o figba kan huwa ifipabanilopọ ti wọn n sọ, o ni akọsilẹ toun buwọ lu ki i ṣe ifẹ-inu oun, wọn fipa mu oun ni, ninu ijaya (under duress) bii aṣa awọn oloyinbo, lo ni oun ti tọwọ bọwe, ki wọn ma baa ṣe oun leṣe ju bẹẹ lọ.
Baba Ijẹṣa ni lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, ti Inpẹkitọ Abigail Oname de si ile Princess, iyẹn lọjọ ti wọn mu oun, Princess ti tọju awọn gende kan pamọ sinu ile naa, awọn ni wọn kọkọ jade soun ki Princess too wọle, ti wọn si sọ ọrọ oun di igbaju igbamu ti kẹrikẹri n ba rode.
O ni bi wọn tun ṣe mu oun jade nile naa, awọn bọis kan tun ya bo oun, ti wọn bẹrẹ si i fi igi ati ẹṣẹ lu oun, ọkan ninu wọn tiẹ re oun lẹpa, ọpẹlọpẹ Inspekitọ Onome to de sakiko naa lo gba oun silẹ, oun lo yọ oun lọwọ wọn, tori ero bii ki wọn pa oun lọjọ naa lawọn to n lu oun ni lọkan. O ni awọn ọlọpaa to wa lọjọ naa ni wọn fi ọkada gbe oun lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Sabo, ni Yaba, ti wọn si ti oun mọle, lẹyin ti wọn ti tun ankọọfu ọwọ oun kuro.
Nigba ti Agbẹjọro olupẹjọ, Yusuf Sule, tun beere ọrọ lọwọ afurasi ọdaran naa, Omiyinka ni oun ko tilẹ mọ adirẹsi ile ti iṣẹlẹ naa ti waye rara, tori ile tuntun ti Princess ṣẹṣẹ ko si ni, oun o si debẹ ri yatọ si ọjọ iṣẹlẹ yii, o ni ile ti Princess n gbe tẹlẹ loun mọ. Ṣugbọn o fidi ẹ mulẹ pe orukọ oun, orukọ baba oun, iya oun, ileewe pamari ati sẹkọndiri toun lọ, ati akọsilẹ bi ko ṣe le pari ẹkọ rẹ ni Fasiti Eko (UNILAG) to wa ninu akọsilẹ naa tọna, o ni ko sirọ ninu awọn yẹn.
Ṣugbọn nigba ti Lọọya Yusuf bi i leere pe bawo lawọn agbofinro ṣe waa mọ gbogbo awọn orukọ ati itan igbesi aye ẹ daadaa to bẹẹ, to si gba pe wọn tọna, ti ki i baa ṣe pe oun lo ba wọn sọrọ, nibo waa ni wọn ti ri eyi to tọna ninu akọsilẹ naa, Baba Ijẹṣa ko fesi si ibeere yii. Lọọya naa tun beere bakan naa lẹẹmeji ati lẹẹkẹta, ṣugbọn ko fesi, ọọkan gan-an lo n wo bii ẹni to n wo sinima.
Tẹ o ba gbagbe, ninu awọn igbẹjọ to ti waye ṣaaju ni Inspẹkitọ Abigail ti sọ nile-ẹjọ pe awọn o fiya jẹ afurasi ọdaran naa, ẹnikẹni ko si fipa mu un lati sọrọ tabi buwọ-luwe, wọn loun funra ẹ lo jẹwọ ohun to ṣe, tawọn si ba a kọ ọ silẹ, awọn ka a si i leti nigba ti wọn kọ ọ tan, awọn si bi i leere pe boya o loye akọsilẹ naa ati boya o fara mọ ọn ko to o buwọ lu u, o si gba pẹlu awọn.
Ṣa, Adajọ Oluwatoyin Taiwo ti sun igbẹjọ to ku siwaju.