Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti faago ikilọ bọnu pe latari bi pọpọṣinṣin ọdun Keresi ati ọdun tuntun ṣe n kanlẹkun gbọngbọn yii, o ṣee ṣe ki arun aṣekupani nni, Koronafairọọsi, tun gbinaya lẹẹkẹrin nipinlẹ Eko, tori naa, wọn fẹ ki kaluku wa lojufo, ki wọn ma si ṣe tura silẹ lori ọrọ ọhun.
Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, lo sọrọ yii fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, lasiko to n ṣalaye ibi ti tijọba ba iṣẹ de lori arun naa nipinlẹ Eko.
O ni akiyesi ati iwadii ti fihan pe asiko pọpọṣinṣin ọdun ni arun Korona maa n fẹla, tori ifarakinra ati awẹjẹ-wẹmu, ariya ọlọkan-o-jọkan to maa n pọ lawọn asiko bẹẹ.
O ni ipinlẹ Eko ni pataki maa n gbalejo awọn arinrin-ajo rẹpẹtẹ ti wọn fẹẹ waa ṣọdun nile pẹlu awọn ọrẹ ati mọlẹbi wọn nipinlẹ ọhun, ati pe awọn ẹnubode pupọ lo yi ipinlẹ Eko ka, eyi tawọn ara ilẹ okeere le gba wọle, lara ẹ ni papakọ ofurufu ati etikun.
Ohun mi-in ti ikilọ yii ko fi gbọdọ jẹ agbọ-gbọnti-nu ni pe ida meji aabọ pere ninu ọgọrun-un (2.6 per cent) awọn olugbe ilu Eko lo wa lakọọlẹ pe wọn ti gba abẹrẹ ajẹsara to n dena arankalẹ arun Korona, o ni ọpọ eeyan ṣi n fi ọrọ abẹrẹ naa pa mi-in-din ni.
O ni ijọba Eko ti bẹrẹ igbesẹ lati ri i pe ida ọgbọn lori ọgọrun-un olugbe ipinlẹ Eko gba abẹrẹ ajẹsara naa laarin ọdun kan.
Dokita Abayọmi parọwa sawọn araalu pe ki wọn tete lọọ gba abẹrẹ ajẹsara yii lawọn ibudo tijọba ṣeto kaakiri ipinlẹ Eko, lai fakoko ṣofo mọ.
O tun rọ wọn lati ma ṣe tura silẹ lori pipa awọn alakalẹ ati ofin idena arun Korona mọ, bii fifọwọ loorekoore, lilo ibomu nigba gbogbo, yiyẹra fun ikorajọpọ ero, ati lilo awọn oogun apakokoro ti wọn n pe ni sanitaisa.