Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awobinrin Ọṣunbukọla Ọlọṣun-Ẹlẹbuibọn ti sọ pe ipinlẹ Ọṣun ko deede jẹ ipinlẹ alaafia bi ki i baa ṣe ti irubọ oorekoore ti awọn ẹlẹsin ibilẹ, paapaa, awọn Ọlọṣun n ṣe.
Nibi ayẹyẹ ọdun Ọṣun ati ti awọn Ẹgbẹ-Ọrun ti ọdun yii to waye niluu Oṣogbo ni Ọṣunbukọla ti ṣalaye pe ileri Ọṣun lati ọdun pipẹ ni pe oun yoo maa daabo bo awọn eeyan ilu Oṣogbo atipinlẹ Ọṣun lapapọ.
O ni Ọṣun ko yẹ ninu imuṣẹ ileri rẹ ri pẹlu bi alaafia ṣe n jọba nipinlẹ Ọṣun, idi si niyẹn ti awọn fi korajọ lati dupẹ lọwọ Ọṣun fun awọn idagbasoke oniruuru to n ṣẹlẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi nibi ọdun naa, “A dupẹ lọwọ Olodumare ati Ejidinlogun irunmọlẹ. Ọdun idupẹ niyi fun Yeye Ọṣun fun aabo rẹ lori ilu Oṣogbo ati ipinlẹ Ọṣun lapapọ.
“Lati aimọye ọdun ni Ọṣun ti ṣeleri lati maa mu wa dagbasoke niluu Oṣogbo, o si n mu ileri rẹ ṣẹ lai fi ti ọpọlọpọ ọta to yi wa ka ṣe.
“A kora jọ pọ nibi lonii lati fi ẹmi imoore wa han si Yeye Ọṣun fun alaafia ati itẹsiwaju to n ba ipinlẹ Ọṣun. Awa ẹlẹsin ibilẹ, paapaa, awa Ọlọṣun la wa nidii alaafia to n jọba yii nipasẹ irubọ loorekoore si awọn irunmọlẹ.
“Nitori naa, a ke si ijọba ipinlẹ Ọṣun lati ṣe afikun iranlọwọ to n ṣe fun awọn ọdun ibilẹ gbogbo nitori wọn tun le jẹ orisun ipawowọle labẹnu funjọba.
“Bakan naa ni mo ke si awọn ẹlẹsin to ku lati wo awokọṣe rere lara awa ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ yii, ki iṣọkan ati ifẹ tootọ pẹlu ifarada le wa fun idagbasoke ipinlẹ wa”
Lara awọn ti wọn wa nibi eto naa ni Iyaafin Ẹgbẹyẹmi Ẹlẹbuibọn atawọn eeyan nla nla mi-in ninu ẹsin ibilẹ.