Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Titi di asiko ti a n kọ iroyin yii ni awọn agbofinro atawọn ẹṣọ ibilẹ to ku ṣi n wa Oloye Donatus Okereke to jẹ Eze Ndigbo Ifọn.
Ọkunrin yii la gbọ pe wọn da lọna lagbegbe Ẹlẹgbẹka, nijọba ibilẹ Ọsẹ, lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lojuko ibi ti wọn ti yinbọn pa Olufọn tilu Ifọn, Ọba Israel Adeuti, lọdun to kọja.
Asiko ti gbajugbaja oniṣowo ọhun de iyana ileeṣẹ Kuari ni wọn lawọn ajinigbe naa deede fo jana, ti wọn si n yinbọn soke kikan kikan lati fi dẹruba awọn eeyan to le fẹẹ ko wọn loju.
Laarin iṣẹju ayaa ni wọn wọ ọkunrin naa jade kuro ninu ọkọ jiipu rẹ, ti wọn si fipa wọ ọ wọnu igbo lọ.
Ọkan ninu awọn olori ilu Ifọn, Ọgbẹni Ọlaniyi Ẹni Olotu fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ f’ALAROYE nigba ta a kan sí í lori aago.
O ni yatọ si pe wọn ji olori awọn Igbo ọhun gbe sa lọ, gbogbo owo ti wọn ba ninu ọkọ rẹ ni wọn tun ji ko lọ.
O ni Adele-Onifọn ti fi iṣẹlẹ ọhun to ọlọpaa atawọn ẹṣọ Amọtẹkun leti ki wọn le gbe igbesẹ to yẹ nipa rẹ.