Faith Adebọla
Beeyan ba kọkọ wo bi obinrin ẹni ọgbọn ọdun yii ṣe da hijaabu bori gẹgẹruru, agba ẹsin Musulumi leeyan yoo pe Abilekọ Fatima Lawali. Ṣugbọn nigba tawọn agbofinro mu un, ti wọn si ni ko ka hijaabu rẹ soke, ọta ibọn AK-47 ti wọn o ti i yin lobinrin yii bo mọ abẹ aṣọ rẹ to n gbe lọ, o lawọn janduku agbebọn loun n lọọ pin in fun ninu igbo.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, CP Ayuba Elkanah, lo sọrọ yii di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, nigba to n ṣafihan afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin. O ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ aarọ ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni ọga ọlọpaa DSP Hussaini Gimba ṣaaju ikọ ọtẹlẹmuyẹ lẹyin ti olobo ta wọn pe Fatima Lawali n ko ohun ija oloro lọ fawọn agbebọn gẹgẹ bii iṣe rẹ.
O lọwọ ba ọmọ bibi ijọba ibilẹ Kaura Namoda yii ninu igbo to wa laduugbo Gada Biyu, lagbegbe ijọba ibilẹ Bungudu. Ọta ibọn ayin-tunyin rẹpẹtẹ ti wọn ba lọwọ rẹ jẹ ẹgbẹrun kan din mẹsan-an (991). Inu aṣọ kan ti wọn ran bii apo lo di ẹru ofin naa si, lo ba gbe apo naa kọpa, o da hijaabu bo o, o n lọ kemọkemọ.
Kọmiṣanna ni nigba tawọn agbofinro bẹrẹ iwadii, obinrin naa jẹwọ pe ipinlẹ Sokoto loun n gbe awọn nnkan ija oloro naa lọ, o ni agbebọn kan to n jẹ Ado Alero loun fẹẹ lọọ gbe e fun. Ado Alero yii ni wọn lo wa nidii ọpọ akọlu awọn agbebọn to n ṣẹlẹ nipinlẹ Zamfara atawọn ipinlẹ to yi i ka.
Wọn lobinrin ọdaran yii jẹwọ pe o ti pẹ toun ti n ṣiṣẹ buruku naa, o ni gbogbo awọn inu igbo agbegbe ọhun lohun mọ apade alude wọn, oun si ti maa n ṣiṣẹ biba awọn agbebọn ko nnkan ija oloro wọle, paapaa ọta ibọn, lawọn ipinlẹ Niger, Kaduna, Kebbi, Sokoto, Zamfara ati Katsina, ti wọn si n foun lowo gidi.
Ayuba ni ọwọ tun ba awọn afurasi ọdaran mi-in ti wọn n ṣe agbodegba fawọn afẹmiṣofo ajinigbe wọnyi. Lara wọn ni Ọgbẹni Babuga Abubakar ati Lawali Kabiru, ti wọn fẹsun kan pe ofofo lawọn maa n ṣe fawọn janduku ọhun.
Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ṣe wi.