Faith Adebọla, Eko
Ilu Jeddah, lorileede Saudi Arabia, ni obinrin ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta yii, Abilekọ Afusat Ọlayinka Adisa, dagbere, diẹ lo si ku ko wọ baaluu l’Abuja, ṣugbọn aṣiri tu pe egboogi oloro wa nikun obinrin naa, koro egboogi kokeeni (cocaine) ọgọrin ni wọn lo ya mọ’gbẹẹ, ni wọn ba mu un.
Alukoro apapọ fun ileeṣẹ NDLEA to n gbogun ti lilo ati ṣiṣowo egboogi oloro nilẹ wa (National Drug Law Enforcement Agency), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aje, Mọnde yii, o ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, lọwọ ti ba afurasi ọdaran yii lọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, iyẹn ọjọ Wẹsidee, ọsẹ to kọja.
Afusat, ọmọ bibi ilu Ilọrin, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ni wọn lo n gbe ilu Ibafo, nipinlẹ Ogun. Obinrin naa fẹẹ wọ baaluu Qatar Airways 1418 kan lọ siluu Mẹka, to loun ti fẹẹ lọ ṣẹsin fun Allah.
Babafẹmi ni ẹrọ atanilolobo lo taṣiiri obinrin naa, wọn niṣe lẹrọ naa n han goororo nigba to fẹẹ gba ile ayẹwo ọhun kọja, leyii to fihan pe o lẹbọ lẹru.
Lẹyin mẹta ti wọn fi i si ahamọ wọn, iyẹn lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, Afusat yagbẹ, wọn si ba egboogi oloro kekeeni to gbe mi ni
nu igbẹ ẹ.
Wọn lobinrin naa jẹwọ pe loootọ loun n ṣowo egboogi oloro, o ni ọdọ awọn eeyan mẹfa kan loun ti ra awọn egboogi naa laduugbo Akala, ni Mushin, nipinlẹ Eko, ni miliọnu meji aabọ naira (N2.5 million).
Ki lobinrin yii lọbẹ to fi waro ọwọ? Babafẹmi ni afurasi ọdaran naa jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe airọmọbi lo sun oun dedii gbigbe egboogi oloro. O lọdun mejidilọgbọn (28) loun ti wa nile ọkọ toun ko ni oyun aarọ di alẹ ri.
O ni miliọnu meje naira ni wọn ni koun wa lati le lo ilana iṣegun igbalode kan ti wọn n pe ni IVF (In-Vitro Fertilization), koun le bimọ, nigba ti gbogbo aajo toun atọkọ oun n ṣe lati lọmọ laye n ja si pabo. Owo yii loun n wa ti obinrin kan fi juwe okoowo egboogi oloro foun, tori aṣọ loun n ta tẹlẹ. O loun yawo ni, miliọnu kan naira loun ya lati le fi ra egboogi ọhun, oun si fẹẹ lọọ ta a siluu oyinbo ni.
Ṣa, wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii.