Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko din leeyan mẹrinlelọgọfa ( 124) ti ọwọ ijọba ipinlẹ Ogun tẹ l’Ọjọbọ to kọja yii fun pe wọn n ṣegbọnsẹ sibi ti ko tọ, wọn ko si tẹle ofin imọtoto.
Bi wọn ṣe mu wọn kaakiri awọn agbegbe nipinlẹ Ogun ni wọn ti ṣe idajọ wọn lẹsẹkẹsẹ, nipa fifun wọn ni agbegbe lati tunṣe.
Mowe-Ibafo, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ni wọn ti ko awọn to n ṣegbọnsẹ kiri ibi ti ko tọ naa ju. Eeyan mejilelọgọrin ( 82) lọwọ ba lawọn agbegbe mejeeji yii nikan.
Nigba to n sọrọ nipa awọn onigbọnsẹ ẹba ọna, kanaali, oju opopo ati koto idaminu yii, Oludamọran pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun nipa ayika, Ọgbẹni Ọla Ọrẹsanya, ṣalaye pe oru la a ṣẹka lawọn ti wọn n ṣegbọnsẹ naa fi n ṣe.
O ni ọwọ alẹ ati idaji kutu lawọn to n yagbẹ sibi ti ko tọ yii maa n ṣe bẹẹ ju, bẹẹ, ipa buburu ni igbọnsẹ ṣiṣẹ kaakiri yii n ni lori ilera awọn eeyan to wa lagbegbe, paapaa lasiko yii ti awọn arun buruku n ja kiri agbaye.
O lohun to buru ni bawọn kan ṣe tun fẹẹ maa fi tiwọn ko ba ilera awọn eeyan yooku, ijọba ko si ni i gba fun wọn lawọn ṣe tete n ṣa wọn kiri bayii.
Ọrẹsanya to tun jẹ ọga OGWAMA, iyẹn ajọ akolẹ-kodọti nipinlẹ Ogun, tẹsiwaju pe awọn awakọ to n rin loru, ti wọn saaba maa n duro lawọn ibudo kọọkan lati sinmi naa maa n huwa aitọ yii. O ni ki wọn yee lo asiko naa lati yagbẹ sẹgbẹẹ ọna tabi laarin titi, agaga awọn awakọ Mowe-Ibafo, nibi ti ẹgbin naa pọ si ju lọ.
Ọga OGWAMA ni ki wọn maa lo awọn ile igbẹ apapọ (public toilet) tijọba kọ kiri.
Mimu ti wọn mu wọn yii ki i ṣe ohun ti yoo dawọ duro gẹgẹ bi Ọrẹsanya ṣe wi, o ni ijọba ti bẹrẹ ẹ na, bẹẹ ni yoo si maa ri lọ ti wọn yoo maa mu awọn arufin wọnyi, wọn yoo si maa fi wọn jofin bo ṣe yẹ.
Ọrọ imọtoto yii kan awọn ileepo atawọn ile ounjẹ igbalode( eatery). Ọrẹsanya sọ pe o ti di dandan bayii kawọn ileepo atawọn ile ounjẹ igbalode maa gba awọn alarekọja yii laaye lati lo ileegbọnsẹ wọn fun itura, eyi yoo maa jẹ ara ojuṣe tiwọn naa fun ilu ( Corporate social responsibility).
Ile igbọnsẹ ajọlo to le lọgọrun-un lo ni ijọba ipinlẹ Ogun ti la kalẹ lati kọ si i bayii, ti wọn ti ya aaye ti wọn yoo kọ ọ si sọtọ, lati gbogun ti igbọnsẹ ṣiṣe kaakiri yii naa ni.
O waa rọ gbogbo ile, adugbo ati agbegbe lati ti ijọba lẹyin, ki wọn le jọ gbogun ti ajakalẹ arun to n tidi igbọnsẹ ṣiṣe lọna aitọ wa.