Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ipinlẹ Ekiti ti padanu ẹni kẹta sọwọ arun Koronafairọọsi pẹlu bi awọn to lugbadi arun naa ṣe di mẹrinlenigba (204) nipinlẹ naa bayii.
Lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, nijọba ipinlẹ naa kede pe eeyan mẹrin ninu awọn ti wọn ṣẹṣẹ ṣayẹwo ni wọn ti ko arun ọhun, eyi si ti sọ awọn to wa nibudo itọju bayii di mejidinlaaadọfa (108).
Nitori bi arun yii ṣe n tan kalẹ diẹdiẹ nipinlẹ naa nijọba ṣe mu ofin tita kete sira ẹni ati lilo ibomu lọkun-un-kundun, awọn alakalẹ yii si mulẹ gidigidi.
Lọwọlọwọ bayii, eeyan mẹtalelaaadọrun-un (93) lo ti ri iwosan l’Ekiti, eyi to din diẹ ni ida aadọta awọn to ti ko arun naa nipinlẹ ọhun.