Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki ijọba ipinlẹ Ọṣun pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan kawọ ro lori yiyan Olufọn ti ilu Ifọn Orolu tuntun.
Alhaji Ọmọọba Sulaiman Akinyọọye, Ọmọọba Peter Oluwọle Akinyọọye, Ọmọọba Jide Akinlaja Akinyọoye, Ọmọọba Muideen Ọlarinde ati Ọmọọba Muideen Akinloye lati idile Morohunfolu nile ọlọmọọba Ọlaọjọ ni wọn gbe ẹjọ naa lọ si kootu.
Awọn ti wọn si pe lẹjọ ni Ọmọọba Wahabi Oyegbile (latidile Ọdunolu ninu ile ọlọmọọba Ọlaọjọ), Gomina ipinlẹ Ọṣun, kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ọṣun, kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ati alaga ijọba ibilẹ Orolu.
Awọn yooku ni Oloye Agba Oyetunde Oyetunji to jẹ Eesa Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Amusa Majoyegbe Ọlaawin to jẹ Aajẹ Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Julius Oyeleke to jẹ Elesi ti Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Moshood Adeoye to jẹ Ikọlaba ti Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Adamọ Akintunde yo jẹ Ẹjẹmu ti Ifọn Ọṣun ati Oloye Agba Lamulatu Afọlabi to jẹ Iyalode ti Ifọn Ọṣun.
A oo ranti pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kọ lẹta si ile ọlọmọọba Ọdunolu lati fi orukọ ẹni ti yoo di Olufọn ranṣẹ, eleyii ti awọn idile Ọlaọjọ ri bii ọna lati fi ẹtọ wọn du wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ṣe nijọba gboju kuro lara akọsilẹ ilana jijẹ ọba ilu naa, eleyii ti wọn ṣatunṣe si lọdun 1988, ṣugbọn ti wọn fẹẹ lo ti ọdun 1979, idi si niyi ti wọn fi gba kootu lọ.
Ninu idajọ to tẹ Alaroye lọwọ, Onidaajọ A. O. Oyebiyi sọ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun atijọba ibilẹ Orolu ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lori ọrọ yiyan ọba ilu naa titi ti wọn yoo fi yanju ẹjọ to wa ni kootu.