Awada lasan lawọn to ni mo n ṣatileyin fun Tinubu lati di aarẹ n ṣe – AKINTOYE

Laipẹ yii ni iroyin kan jade, pe baba agba nni, Ọjọgbọn Banji Akintoye, to n pe fun orilẹ-ede Olominira Yoruba ti darapọ mọ awọn ti wọn n fẹ ki Aṣiwaju Bọla Tinubu di aarẹ Naijiria ni 2023. Esyi ni Ọjọgbọn naa ṣe ṣalaye bi ọrọ ọhun ṣe jẹ gan-an.

Ninu fọn-ọn-ran ohùn kan ti Baba Akintoye fi ranṣẹ s’ALAROYE lo ti ṣalaye pe awọn ti wọn ni oun n tẹlẹ Tinubu kan fi ọrọ naa ṣe awada lasan ni, ko sohun to jọ bẹẹ.

 

Baba tẹsiwaju pe loootọ ni Yoruba ko le dẹyẹ si Tinubu, nitori ọmọ wa naa ni. O ni ṣugbọn pe oun n ṣatilẹyin fun un lati di aarẹ ni 2023 ko ri bẹẹ, nitori Yoruba ko ni i dibo ni Naijiria ni 2023, ilẹ Olominira Yoruba  tawọn n ja fun yoo ti wa nigba yẹn, yoo si jẹ pe Yoruba Nation ti Yoruba n ja fun ti de.

 

“Awọn ọmọ Tinubu lo n ṣawada, ti wọn ni emi Banji Akintoye n ṣatilẹyin fun un lati di aarẹ. A o gbọdọ binu si wọn, ka kan fi rẹrin-in ni… Ṣugbọn iṣẹ ta a fẹẹ ran si ọga wọn ni pe ki i ṣe awada, awa Yoruba ti pinnu ibi ti a n lọ, Oodua Nation la n wa.

 

“Ibi to dẹ yẹ ko o waa lo gbogbo oṣelu to o ti ṣe ati gbogbo agbara to o ti ni si niyẹn. A n reti ẹ o, Aṣiwaju, ẹgbọn ẹ Banji lo n ba ẹ sọrọ yii o, maa bọ.

“Wa sibi tawọn eeyan ẹ wa, awa o ki i ṣe Naijiria mọ o, ko ni i si idibo nilẹ wa mọ, ibo ti yoo ba waye bayii yoo jẹ ti Ilẹ Olominira Oodua ni. Maa bọ waa darapọ m’awọn eeyan ẹ. Asiko ti to ko o wale”

Bẹẹ ni Ọjọgbọn Akintoye fohun ranṣẹ si Tinubu, ti baba ni ki Jagaban ma fi ilẹ Yoruba ati anfaani ibẹ du ara rẹ, ile too lọ.

Leave a Reply