Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Obinrin alaaganna kan, Olajiga Ṣekẹmi, ẹni ọgbọn ọdun, to ṣa ọmọ ọdun meje kan pa niluu Ado-Ekiti, ladajọ ti paṣẹ pe ko maa lọ si ọgba ẹwọn fun igba kan na.
Bakan naa ni ile-ẹjọ naa tun paṣẹ pe ki iya ati baba obinrin alaaganna yii, Olajiga Victoria ati Ọlajiga Banji, maa tẹle ọmọ wọn yii lọ si ọgba ẹwọn bakan naa.
Onidaajọ Michael Faola lo paṣẹ pe ki wọn maa lọ si ọgba ẹwọn titi di igba ti esi yoo jade lati ileeṣẹ to n gba ile-ẹjọ nimọran.
Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii, lawọn ọlọpaa gbe obinrin were yii ati awọn obi rẹ mejeeji yii wa siwaju ile-ẹjọ naa.
Agbefọba ile-ẹjọ naa, Insipẹkitọ Bankọle Ọlasunkanmi, ṣalaye pe awọn ọdaran metẹẹta naa lọwọ ninu iku ọmọ ọdun meje kan, Demilade Fadare, ni ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ọdun 2021 yii.
Agbefọba ko iwe ti awọn ọdaran naa kọ ni teṣan ti wọn fi jẹwọ pe loootọ lawọn ṣẹ ẹṣẹ naa. O ṣalaye pe baba ọmọdebinrin lenjelenje yii, Ọgbẹni Fadare Oluwaṣọla, lo lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa lẹyin ti wọn ti wa ọmọdebinrin ti iya rẹ ran ko lọọ ra ògì wa ni alẹ ọjọ naa ti wọn ko ri i.
Agbefọba yii fi kun un pe teṣan ibi ti baba ọmọdebinrin yii ti waa fọrọ naa lọ ni awọn mọlẹbi rẹ ti pe e, ti wọn si fi to o leti pe wọn ti ri oku ọmọ naa ni ile kan lara ile awọn alabaagbe rẹ ni adugbo naa.
Agbefọba yii sọ pe ẹṣun ipaniyan ti wọn fi kan wọn yii lodi sofin ipinlẹ Ekiti tọdun 2012.
Adajọ Michael Faola paṣẹ pe ki awọn odaran naa maa lọ si ọgba ẹwọn, ẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022.