Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ Majisireeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti bẹrẹ igbẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan agba ṣọrọṣọrọ nni, Oloye Gbenga Filani, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Owuyẹ.
Afurasi ẹni ọdun mẹtadinlọgọta naa ni wọn fẹsun meji ọtọọtọ kan lasiko to n fara han ni kootu ọhun lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Olujẹjọ ọhun ni wọn fẹsun kan pe o ba ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan ti wọn porukọ rẹ ni Ojo Bukọla lo pọ lodi si ifẹ inu olupẹjọ.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan an pe o kan ọmọ naa labuku pẹlu bo ṣe fọwọ kan oju ara rẹ lọna ti ko bofin mu.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye ninu ijọ Sẹlẹ to wa laduugbo Owuyẹ, Opopona Ọda, Akurẹ, ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun yii.
Ẹsun mejeeji ti wọn fi kan olujẹjọ ni wọn lo lodi labẹ abala ofin ọtalelọọọdunrun din mẹta (357), ọtalelọọọdunrun din meji (358) ati ọtalelọọọdunrun (360) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Ninu ẹbẹ rẹ, Agbefọba Akintimẹhin Nelson ni awọn ni ẹri to daju lati fi ba afurasi naa ṣẹjọ, o ni lara ẹri awọn ni ọmọbinrin to jẹ olupẹjọ ati aṣọ meji ti awọn ri nile rẹ lasiko ti wọn lọọ yẹ ẹ wo.
Akintimẹhin ni ki kootu ọhun paṣẹ ki wọn fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn na, nitori pe kootu Majisreeti ko lẹtọọ labẹ ofin lati gbọ iru ẹsun ti wọn fi kan an.
O ni o lewu pupọ fun awujọ ti adajọ ba lọọ fi aaye beeli rẹ silẹ nitori pe o le sa lọ tabi ko tun lọọ daran mi-in.
Kiakia ni Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin Akinrata Adelankẹ, ti dide, to si ta ko ẹbẹ agbefọba.
Agbejoro ọhun ni gbogbo ẹri ti agbefọba n pariwo pe oun ni ko to rara lati tori rẹ fi onibaara oun sọgba ẹwọn.
O waa rọ ile-ẹjọ lati faaye beeli silẹ fun olujẹjọ, o ni awawi lasan lọrọ ti agbefọba n sọ pe o ṣee ko sa lọ.
Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni, faaye beeli Gbenga Filani silẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (#500,000) pẹlu oniduuro meji.
Ninu ọrọ diẹ ti Owuyẹ raaye b’ALAROYE sọ ni kootu, o ni kayeefi patapata ni gbogbo iṣẹlẹ naa ṣi n jọ loju oun, nitori pe ko sohun to pa oun ati ọmọ naa pọ rara.
O ni akisa ti awọn fi n nu ilẹ lawọn ọlọpaa ko nile oun lọjọ ti wọn waa yẹ ile oun wo, ti wọn si n pariwo pe aṣọ ti oun fi nu oju ara rẹ lawọn ri.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2022, ni adajọ sun igbẹjọ mi-in si.