Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Diẹ bayii lo ku ki oore ti obinrin tiṣa kan torukọ ẹ n jẹ Esther Bada, ṣe di ibi mọ ọn lọwọ l’Owode-Ẹgba, nipinlẹ Ogun. Ọmọ to gba tọ, Tọpẹ Fasanya, ẹni ọdun mejidinlogun, lo fi majele sounjẹ fun un, to si fẹẹ pa a.
Akẹkọọ ileewe girama naa sọ pe nítorí oun fẹẹ pada sọdọ iya oun loun ṣe fẹẹ pa obinrin toun n gbe lọdọ rẹ naa.
Atẹjade ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi fi sita nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu kejila yii, ṣalaye pe Abilekọ Bada lo fẹjọ sun pe Tọpẹ gbe ounjẹ foun, boun si ṣe jẹ ounjẹ naa tan ni inu bẹrẹ si i run oun gidi.
Iya yii loun ba pe Tọpẹ to se ounjẹ ọhun pe ko waa jẹ eyi to ku, ṣugbọn si iyalẹnu oun, niṣe lọmọ naa taku, ti ko jẹ ounjẹ yii. Iya sọ pe nibi ti ara ti fu oun niyẹn.
Ileewosan Jẹnẹra Owode-Ẹgba ni wọn sare gbe Abilekọ Bada lọ fun itọju, lati ibẹ ni wọn ti ni ki wọn maa gbe e lọ si FMC, l’Abẹokuta.
Bi eyi ti n lọ lọwọ lawọn ọlọpaa ti lọọ mu Tọpẹ Fasanya, o kọkọ taku pe oun ko fi nnkan kan sounjẹ alagbatọ oun yii, afi nigba ti wọn taari ẹ sẹka to n gbọ ẹjọ ipaniyan, nibẹ lo ti jẹwọ pe oun fi oogun eku sinu ounjẹ iya yii, ko le baa ku.
Njẹ ki lo de to fi fẹ́ẹ́ pa a, ọmo yii sọ pe oun fẹẹ pada sọdọ iya oun gangan ni, oun ko fẹẹ gbe lọdọ alagbatọ mọ, ko si ṣee ṣe, afi ti alagbatọ yii ba ku.
Iwadii awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe iwe kẹta alakọọbẹrẹ ni Tọpẹ wa ti baba rẹ fi ku, Abilekọ Bada yii ni tiṣa rẹ nigba naa. Iku Baba Tọpẹ lo mu tiṣa rẹ yii pinnu lati ran an lọwọ ki ẹkọ rẹ ma baa duro, latigba naa lo ti mu ọmọ yii sọ̀dọ̀, to n sanwo ileewe rẹ, to si n fun un lounjẹ titi ti Tọpẹ fi di akẹkọọ nileewe girama onipele keji bayii.
Awọn agbofinro beere lọwọ ọmọ yii pe ṣe Abilekọ Bada n fiya jẹ ẹ ni, o si dahun pe ko fiya kankan jẹ oun o, kódà, o fẹran oun daadaa. O ni ko sohun toun fẹẹ tori ẹ pa a ju pe oun fẹẹ pada sọdọ iya oun lọ.
Bi iwadii gbogbo ba ti pari tan lọdọ awọn ọlọ́pàá, kootu ni Tọpẹ n lọ bi wọn ṣe wi.