Florence Babaṣọla
Ọkunrin ọlọkada kan gbẹmi mi, nigba ti ekeji fara pa lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide ijẹta lasiko ayẹyẹ ọdun Ọṣun to maa n waye lọdọọdun niluu Ido-Ọṣun, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, oju-odo ni ọba ilu naa, Ọba Adedapọ Aderẹmi, atawọn ọlọṣun wa nigba tawọn ọdọ kan ti wọn gun ọkada deede ya wọ inu ilu ọhun.
Wọn pọ, wọn si ko oniruuru nnkan ija oloro lọwọ, ko si sẹni to mọ idi ti wọn fi wa, ṣugbọn bi wọn ṣe wọnu ilu lawọn araalu bẹrẹ si i sa kijokijo kiri.
Bi wọn ṣe n wa ọkada niwakuwa naa lo fa a ti meji ninu wọn fi sọ ori mọra ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ. Loju-ẹsẹ la gbọ pe ẹnikan ku laarin wọn, bẹẹ ni wọn gbe ekeji to fara pa lọ sileewosan LAUTECH, niluu Oṣogbo, fun itọju.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, sọ fun ALAROYE pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa nitori ṣe lawọn ọdọ naa lọ siluu Ido-Ọṣun pẹlu oniruuru nnkan ija oloro.
O ni LAUTECH ni wọn kọkọ gbe awọn mejeeji lọ ni kete tijamba naa ṣẹlẹ, nibẹ ni wọn ti sọ pe ọlọkada kan ti ku, nigba ti ekeji n gbatọju lọwọ, bẹẹ ni wọn ti gbe ọkada mejeeji lọ si tesan.