Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ara ọtọ patapata ni isin ọjọ isinmi to kọja yii jẹ fawọn ọmọ ijọ Sọtitobirẹ pẹlu bi oludasilẹ ṣọọsi naa, Wolii Alfa Samuel Babatunde, ṣe fara han fun igba akọkọ nile-ijọsin ọhun lẹyin bii ọdun meji to ti wa lọgba ẹwọn Olokuta lori ọrọ ọmọ ọdun kan to deedee di awati lọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2019.
Ko fi bẹẹ si iwaasu kan bii alara ninu eto isin wọn lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ṣe ni Wolii Alfa kan lo anfaani ipejọpọ naa lati fi sọ awọn iriri rẹ laarin ọdun meji to fi wa lọgba ẹwọn fawọn ọmọ ijọ.
Diẹ ninu awọn iriri ti Wolii Alfa sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ ree.
‘‘Mi o binu ẹnikan, bẹẹ ni mi o ni i ba ẹnikẹni ja, mo ti gba kamu, mo si ti dariji gbogbo awọn ti wọn fiya jẹ mi lai nidii kan pato nitori o pẹ ti Sunny Ade ti kọ ọ lorin pe ‘ẹni t’ Ọlọrun da lẹjọ to loun o gba to n fapa janu, nibo lo fẹẹ gbẹjọ lọ’.
‘‘Ẹbẹ ni mo n bẹ ẹyin ọmọ ijọ mi kẹyin naa dariji wọn, nitori pe ẹkọ nla loun to ṣẹlẹ naa yẹ ko kọ gbogbo wa lati jẹ ka mọ pe lẹyin Ọlọrun, ko tun si eeyan mọ.
‘‘Mi o bẹ ẹnikẹni lọwẹ lati gbeja mi, ọpẹ ni mo fẹ kẹ ẹ maa ba mi da lọwọ Ọlọrun nitori pe ka ni mo ti ku sẹwọn ni, ta ni mo fẹẹ fi ọlọpaa mu.
‘‘Meloo ni mo fẹẹ maa ro, gbogbo nnkan ti mo ni laye lọrun ni wọn ti bajẹ, ọkọ ayọkẹlẹ meje lo wa ninu ọgba ile mi yatọ si ọkọ nla ti mo gbe lọ sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọjọ ti wọn ni ki n kọkọ yọju sawọn, gbogbo rẹ lawọn abinuku mi parẹ patapata, wọn jo sọọsi, ko tẹ wọn lọrun, wọn tun mori le ile mi, nibi ti wọn ti ba ọpọlọpọ nnkan jẹ pẹlu.
‘‘Síbẹ, mi o ni i koriira awọn to ṣiṣẹ ibi yii, mo dariji wọn, mo si n fẹ kẹyin ọmọ ijọ mi naa ṣe bẹẹ gẹgẹ to ba jẹ pe loootọ lẹ jẹ ọmọ Ọlọrun.
‘‘Awọn kan ti n gba mi nimọran pe ki n pe awọn to fiya jẹ mi lọna aitọ lẹjọ, ṣugbọn mo ti pinnu lọkan mi pe mi o ni i ṣe bẹẹ. Ẹ wo o, ẹ ma ro pe ma a maa lọ sori oke lọọ gbadura ta ko wọn, rara o, tẹ ẹ ba ri mi lori oke, ara mi ni mo n lọọ gbadura fun ki Ọlọrun tete da awọn ikolọ mi pada.
‘‘Lati ọjọ kẹsan-an, oṣu kejila, ni wọn ti bẹrẹ ọtẹ ọhun wẹrẹwẹrẹ nitori pe ọjọ naa gan-an lawọn ọlọtẹ kọkọ ko ara wọn jọ lati we irọ ohun ti mi o ṣe mọ mi lẹsẹ.
‘‘Ọjọ kọkanla, oṣu naa, ni wọn waa mu mi nile, ti wọn si ba gbogbo nnkan ini mi jẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu kan naa.
Ki i ṣẹjọ awọn to ba nnkan mi jẹ, eeyan ni n bẹ nidii oro ti oro fi n ke, bi iku ile ko ba pa ni, tode ki i pa ni, bo ṣe ri nigba aye Jesu ti Judasi, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ dalẹ rẹ, bẹẹ gẹlẹ lọrọ temi naa ri, o ye mi yekeyeke pe ajalu to de ba mi lọwọ awọn to sun mọ mi bii iṣan ọrun ninu.
‘‘Kekere ni gbogbo nnkan wọnyi si ohun toju mi ri lọgba ẹwọn, ibọn ni wọn maa n gbe ti mi nigbakuugba ti mo ba ti n gbadura, ti mo ba ni mo fẹẹ lọọ tọ, ogun ni, gbogbo ero wọn ni pe, o ṣee ṣe ki n poora ti wọn ko ba ṣọ mi daadaa.
‘‘Nigba to su mi ni mo pinnu pe mi o ni i jade mọ, fun bii oṣu mẹjọ gbako ni mo fi wa ninu yara ti wọn ti mi mọ lai yọju sita.
Iṣẹlẹ ọhun buru to bẹẹ ti ọkan ninu awọn ọmọ mi ko fi da mi mọ mọ lọjọ kan ti awọn ati iya wọn waa ki mi. Ṣe lo maa n da bii ẹni pe ẹmi fẹẹ jade lara mi ni gbogbo igba ti wọn ba ti n gbe mi lọ si kootu.
‘‘Ẹnu ko gba iroyin ni ti n ba ni ki n maa royin gbogbo ohun ti mo foju wina laarin ọdun meji ti gbogbo iṣẹlẹ wọnyi fi n sẹlẹ si mi.
Idi ree ti mi o fi loun meji ti mo fẹẹ sọ ju ki n kan maa dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn ọmọ ijọ ti wọn duro ti mi gbagbaagba.’’
Ọkan ninu awọn olukọ ewe ti wọn tu silẹ pẹlu Wolii Alfa, Abilekọ Motunrayọ Egunjọbi, naa ko gbẹyin ninu eto isin ọhun, koda oun gan-an lo ṣe ogbufọ fun Wolii laarin bii ogoji isẹju to fi ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ.