Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Tọheeb Akanji gan-an lorukọ ọkunrin yii, ṣugbọn T.Cash lawọn eeyan mọ ọn si nibi iṣẹ awọn to n tun firiiji ṣe. Ni bayii, ẹka to n ri si ẹsun ipaniyan lo wa nipinlẹ Ogun, nitori ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto to gun lọbẹ pa, iyẹn Damilare Babatunde Ọladipupọ(No story), l’Adiyan Gasline, nipinlẹ Ogun.
Ọjọ ọdun Keresimesi ti i ṣe ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kejila yii, lọwọ awọn ọlọpaa teṣan Agbado tẹ Tọheeb, lẹyin ti olobo ta wọn pe ẹnikan ti gun Damilare to jẹ ọmọ ẹgbẹ awakọ kan pa nipinlẹ Ogun.
Aago mejila aabọ oru ni ẹni to pe awọn ọlọpaa naa pe wọn, tohun pe ara ẹ ni Oluọmọ.
Oluọmọ ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oloogbe yii waa ba ẹni to ni otẹẹli Blue Roof, l’Adiyan ṣayẹyẹ ọdun Keresi ni, o ni afi bi ẹnikan tawọn ko mọ ri ṣe gun un lọbẹ pa.
Eyi ni DPO Agbado, CSP Kẹhinde Kuranga, ṣe ko awọn ikọ rẹ leyin lọ si otẹẹli naa, nigba ti wọn debẹ lo ye wọn pe wọn tan oloogbe naa jade ninu otẹẹli ni, wọn si gun un ṣakaṣaka laya, ọwọ ati oju.
Awọn ọlọpaa tun fidi ẹ mulẹ pe ọmọ ẹgbẹ onimọto ti wọn pa naa ko ku lẹsẹkẹsẹ, koda, o ba ẹni to gun un pa naa ja debii pe o gba aṣọ otutu (cardigan) tiyẹn wọ sọrun lara rẹ, o si tun gba ọbẹ to fi gun un pẹlu, ki ẹni to gun un pa naa too sa lọ.
Wọn sare gbe e lọ sọsibitu gẹgẹ bi alaye awọn ọlọpaa, ṣugbọn dokita sọ pe o ti ku.
Pẹlu aṣẹ CP Lanre Bankọle ti i ṣe kọmiṣannaa ọlọpaa Ogun, wọn wa ẹni to pa No story jade, wọn si mu un ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Keresi to paayan naa.
Ẹni tawọn ọlọpaa mu ni Tọheeb Akanji, T. Cash, o si jẹwọ fun wọn pe oun loun gun No story pa, ṣugbọn ẹjọ oun naa kọ, iṣẹ Eṣu ni.
T.Cash ṣalaye fawọn ọlọpaa pe awọn kan ni wọn lu ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin oun, ti wọn tun ṣe e leṣe pẹlu.
O ni ẹni to lu eeyan oun naa loun wa lọ si otẹẹli yii, nigba toun debẹ ni Damilare gbeja ko oun, to fi di pe awọn bẹrẹ si i ja, toun si yọ ọbẹ toun ti mu wa lati ile jade ninu apo, n loun ba bẹrẹ si i fi gun un.
Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (32) ni T.Cash, nigba ti No story to doloogbe jẹ ẹni ọdun mejilelogoji (42).
Wọn ti taari T.Cash sẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaayan, yoo de kootu jẹjọ ipaniyan laipẹ gẹgẹ bi atẹjade ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa mulẹ ṣe sọ.