Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ni awọn ọkunrin mẹrin kan ti wọn ni ikọ adigunjale ni wọn gbadajọ iku nile-ẹjọ giga ilu Abẹokuta. Adajọ Patricia Oduniyi lo paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.
Awọn adigunjale naa ni Wasiu Akanbi, Ọlalẹyẹ Matthew, Adebayọ Adetura, ati Micheal Adesanya.
Bo tilẹ jẹ pe wọn lawọn ko jẹbi ẹsun idigunjale ti kootu tori ẹ gbe idajọ iku kalẹ fawọn yii, ile-ẹjọ sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe wọn jẹbi ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, ole jija ati nini nnkan ija ogun lọwọ lai lẹtọọ lati maa gbe wọn kiri.
Nigba to n ṣalaye nipa awọn ẹsun to mu idajọ iku wa yii, Agbefọba T.O Adeyẹmi sọ pe ọjọ karun-un, oṣu kejila, ọdun 2015, lawọn olujẹjọ mẹrin yii huwa to lodi sofin.
O ni ni nnkan bii aago meji-aabọ oru ọjọ naa ni wọn digun wọ opopona Catholic, n’Ibafo, nipinlẹ Ogun.
Agbefọba Adeyẹmi ṣalaye pe awọn ikọ adigunjale yii gbe ibọn atawọn nnkan ija to le gbẹmi eeyan wọ ile Idris Muritala, Adepọju Tomilọla, Sunday Olowomakin ati Kayọde Ọpẹyẹmi, wọn si gba awọn dukia wọn lọ.
Agbefọba tẹsiwaju pe wọn gba foonu mẹwaa, kọmputa alaagbeletan meji ati owo lọwọ awọn eeyan ti wọn wọle wọn naa.
Ohun ti wọn ṣe yii ta ko ofin ijọba orilẹ-ede Naijiria, eyi to lodi si keeyan maa gbe nnkan ija oloro kiri tabi keeyan fiya jẹ ẹlomi-in, ijiya to nipọn lo si wa fun un labẹ ofin gẹgẹ bi agbefọba ṣe sọ.
Nigba ti wọn n dahun ibeere kootu pe ṣe wọn jẹbi awọn ẹsun naa tabi bẹẹ kọ, awọn mẹrẹẹrin lawọn ko jẹbi. Ṣugbọn nigba ti Adajọ Patricia Oduniyi wo saakun ọrọ naa lati ọdun 2015 ti wọn ti wa lẹnu ẹ, o sọ pe awọn to ṣewadii iṣẹlẹ yii ṣiṣẹ takun-takun.
Adajọ sọ pe agbefọba to gbe ẹri kalẹ paapaa ṣe bẹẹ debii pe awọn ẹri to ko kalẹ lori ẹjọ naa ko ruju rara, o han kedere pe ọdaran lawọn mẹrin to n jẹjọ yii ni.
Eyi lo ṣe paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun wọn titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn.