Faith Adebọla
Ọkan pataki ninu awọn agbẹjoro to n ṣoju fun gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti wọn n pe ni Sunday Igboho, Amofin Pẹlumi Ọlajẹngbesi, ti kede pe oun ko ṣiṣẹ pẹlu onibaara rẹ mọ. O lawọn ti pin gaari, oun si ti yọwọ oun lati maa ṣoju fun ọkunrin to wa lahaamọ naa.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu ki-in-ni yii, ni Ọlajẹngbesi to jẹ ọga agba ileeṣẹ Law Corridor, sọ ipinnu rẹ di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede loju opo ayelujara fesibuuku rẹ.
“Eyi ni lati kede pe mo ti yọwọ yọsẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn agbẹjọro to n mojuto awọn ẹjọ to kan ẹtọ ọmọniyan Sunday Adeyẹmọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sunday Igboho ati tawọn to n beere fun idasilẹ orileede Oduduwa.
“Inu wa dun pe ileeṣẹ wa ti ṣe awọn aṣeyọri kan lori ọrọ Sunday Adeyẹmọ (Igboho) ati awọn to n ja fun Yoruba Nation. A ti gba awọn eeyan mejila tawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ SSS fimu wọn danrin, ti wọn tẹ ẹtọ wọn mọlẹ, ti wọn si sọ sahaamọ l’Abuja, silẹ, a si tun ṣiṣẹ takun-takun lati yọ babalawo ti ko mọwọ mẹsẹ kuro latimọle awọn SSS yii.
“A ṣi lawọn eeyan meji ti igbẹjọ wọn ṣi n lọ lọwọ ni kootu lori ẹsun ifẹmiṣofo, o daju pe ileeṣẹ wa yoo ṣi maa ba ẹjọ naa lọ titi de ibi ti wọn ba fori ẹ ti si.
“Mo dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin eeyan, paapaa Amofin agba Oloye Yọmi Aliyu, fun iranlọwọ wọn, Ọmọwe Ọlaṣupọ Ojo, fun bi wọn ṣe dari eto, ati Amofin agba Oloye Fẹmi Falana ti wọn ṣatilẹyin fun wa pẹlu amọran wọn. Ṣugbọn nibi tọrọ de yii, emi gẹgẹ bii ẹnikan fi tọwọtọwọ yọwọ mi.
“Ki i ṣe pe mo fẹẹ ja Ọjọgbọn Akintoye kulẹ, bẹẹ ni mi o ni in lọkan lati ko iyan awọn ajijagbara Yoruba Nation kere o, ṣugbọn mo yọwọ mi gẹgẹ bii ẹtọ ti mo ni lati ṣe bẹẹ ni.
Mo reti pe kawọn eeyan bọwọ fun ẹtọ mi, ki n si ṣe ipinnu bi ọkan mi ṣe fẹ.”
Bẹẹ ni Ọlajẹngbesi kọ ọ soju opo ayelujara rẹ.