Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹlẹwọn mẹrin niroyin fidi rẹ mulẹ pe wọn padanu ẹmi wọn ni ọgba ẹwọn agbegbe Kosẹrẹ, niluu ****Ileefẹ, laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lasiko ti wọn n gbiyanju lati sa kuro nibẹ.
Alaroye gbọ pe lasiko ti wọn n ṣe itọju ayika ti wọn maa n ṣe laraarọ (morning sanitation) niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa lawọn ẹlẹwọn ọhun kọkọ kọ lu, ti wọn si ṣe e leṣe, lẹyin naa ni wọn fẹẹ gbiyanju lati sa lọ koo to di pe awọn agbofinro dide si wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lasiko yii ni ibọn ba mẹrin lara wọn, ti wọn si ku loju-ẹsẹ, nigba ti awọn yooku si ti ri nnkan to ṣẹlẹ ni wọn tete sa pada sinu ọgba ẹwọn.
A gbọ pe Alakoso ọgba ẹwọn nipinlẹ Ọṣun, Lanre Amọran, ti ṣabẹwo si ọgba ẹwọn naa lati lọ mọ nnkan to ṣelẹ gan-an.
Alukoro fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Ọṣun, Ṣọla Adeotan, sọ pe oun ko ti i gbọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ naa.
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa, ṣugbọn o beere fun asiko diẹ lati fi ni iroyin kikun nipa rẹ.