Faith Adebọla, Eko
Onigege ara akọwe-kọwura ilẹ wa nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti sọ pe ọrọkọrọ ni iroyin ẹlẹjẹ kan ti wọn n gbe kiri lori ẹrọ ayelujara pe oun ti fọwọ si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati dupo aarẹ orileede yii lọdun 2023, o lawọn agbọrọdun ti ko dakan mọ ni wọn wa nidii ọrọ ọhun.
Ninu atẹjade kan ti Ṣoyinka fi lede lori ọrọ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lo ti ṣalaye pe oun o ti i ronu lori 2023 rara, ko si ṣenikan toun ti i fi lọkan balẹ lati ṣatilẹyin fun, o ni ẹtan ati irọ ni iroyin tawọn eeyan n gbe kiri nipa ọrọ ọhun.
Ṣe lati opin ọsẹ to kọja ni ọrọ kan ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara, tawọn eeyan si n ṣe atagba rẹ pe Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti fontẹ lu Tinubu fun ipo aarẹ ilẹ wa lọdun to n bọ.
Ninu ọrọ naa, wọn ni Ṣoyinka sọ pe oun ti ṣetan wayi lati ṣatilẹyin fun ọrẹ timọtimọ oun tawọn jọ ja ija ẹgbẹ NADECO ta ko iṣejọba ologun nigba kan, oun si ti fara mọ ọn ki ọrẹ oun naa di aarẹ Naijiria.
Ṣugbọn Ṣoyinka fesi, o ni: “Olodo lẹni to kọ ọrọ ti wọn n purọ ẹ mọ mi yii, emi o sọ ohun to jọ bẹẹ nibikibi rara. “Wọn tun ti bẹrẹ niyẹn o, awọn agbọrọdun ti ko mọ nnkan kan, wọn maa fẹẹ lo orukọ ẹni taye ẹ daa ju tiwọn lọ lati fi wa ojuure awọn eeyan. Ọna ti wọn gba kọwe irọ naa fihan pe olodo lẹni to kọ ọ.
“Mo reti pe o yẹ kawọn araalu ti da iroyin ẹlẹjẹ bayii mọ, ki wọn si maa taṣiiri awọn to wa nidii irọ wọnyi sita, alainilaari ọmọọta kan ni wọn.
“Ki n ma tan yin, mi o ti i ronu kan ọdun 2023, ka ma ṣẹṣẹ sọrọ ti ẹni to fẹẹ du ipo pataki kan. Awọn to n fi ọrọ yii ṣọwọ ko ṣe ara wọn ati ẹni ti wọn fi ranṣẹ si lanfaani. Niṣe ni ki wọn wa nnkan gidi lati fi akoko wọn ṣe.
“Ko tiẹ sọrọ nibẹ rara, ko si eyi to kan wa ninu ọrọ oṣelu lasiko yii, tori ilu awọn oku la wa, lati ọdun to kọja yii lemi gan-an ti n wo ara mi bii oku.
“Awọn oniranu yii naa ni wọn lọọ gbọna ẹyin wọnu imeeli (email) mi, ti wọn si n sọ pe mo ti ku. Kin ni wọn tun fẹ kẹni ti wọn sọ pe o ti ku tun fọwọ si oloṣelu fun?”
Bẹẹ ni Ṣoyinka sọ.