Jọkẹ Amọri
Lati le mu ki igbesẹ lati tete yan Olubadan mi-in sori oye ya kankan, igbimọ Olubadan ti tun fi ipade mi-in si ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ti ireti wa pe wọn yoo ti yanju ọrọ ẹjọ ti wọn gbe lọ si kootu lori ọrọ oye ti Sẹnetọ Isiaka Ajimọbi fi awọn kan ninu wọn jẹ.
Tẹ o ba gbagbe, lara ohun ti wọn fẹnu ko le lori nigba ti wọn ṣepade pẹlu Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ni pe ki wọn lọọ yanju ọrọ ẹjọ to wa ni kootu naa, ki wọn si ma ṣe ri i bii pe ẹni kan lo bori, ẹni kan ni ko bori. Ki awọn eeyan naa mu gbogbo ohun to le mu idiwọ si yiyan Olubadan tuntun kuro lọna.
Lara ẹjọ to n da ifọwọsi Olubadan tuntun gẹgẹ bii ọba ni eyi ti awọn oloye Ibadan naa atawọn Baalẹ ti wọn ti gbega si ipo ọba lọdun 2017 pe ta ko bi wọn ṣe ni ki wọn ko ade naa kalẹ, ki onikaluku wọn si pada si orukọ to n jẹ tẹlẹ.
Eyi ni ko tẹ awọn Baalẹ atawọn oloye Olubadan yii lọrun. Niṣe ni won yari pe awọn ko le gbe ade naa silẹ. Awijare wọn ni pe awọn ko si nibẹ nigba ti wọn n ṣepade pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde lori pe ki awọn gbe ade naa silẹ lọjọ naa lọhun-un, wọn ni wọn ko pe awọn si i, bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa kan awọn gbọngbọn.
Awọn igbimọ Olubadan pẹjọ ta ko aba yii, bẹẹ ni awọn Baalẹ ti wọn gbe ga si ipo ọba naa pẹjọ. Ẹjọ yii lo mu ki agba lọọya kan, Micheal Lana, kọwe si Gomina Ṣeyi Makinde ni kete ti Ọba Saliu Adetunji ku pe ko ma gbe igbesẹ kankan lori fifọwọ si ọrọ Olubadan tuntun nitori to ba ṣe bẹẹ, o n tapa si aṣẹ ati ofin ile-ẹjọ ni.
Ọrọ yii lo di ariwo, bawọn kan ṣe n sọ pe bẹẹ lo ri, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ko sohun to buru lori bi awọn igbimọ Olubadan naa ṣe di ọba.
Wahala ti ọrọ ọhun da silẹ lo mu ki awọn eeyan naa ṣepade pẹlu gomina Ọyọ, ti iyẹn si sọ nibi ipade naa to waye ni Satide ọsẹ to kọja pe ki wọn ma jẹ ko jẹ ile-ẹjọ ni yoo ba wọn yanju ọrọ naa, gbogbo ohun ti wọn ba le ṣe lati gba alaafia laaye, ti ohun gbogbo yoo si fi pada si bo ṣe yẹ ko wa ni ki wọn ṣe.
Lẹyin ipade naa ni Agba-Oye Rashidi Ladọja ba awọn oniroyin sọrọ, nibi to ti sọ pe gbogbo fa-a-ka-ja-a to wa lori ọrọ yiyan Olubadan lawọn ti yanju. Ti ọrọ ofin to si wa nibẹ naa yoo niyanju, bẹẹ lo kede pe Oloye Lekan Balogun ni Olubadan tuntun.
Bakan naa ni awọn ijoye Ibadan yii naa ni awọn ti gba lati gbe ade ti Ajimọbi fun awọn silẹ, ki awọn si wa nipo igbimọ Olubadan bo ṣe wa tẹlẹtẹlẹ.
Ipade ti wọn yoo ṣe lọjọ Iṣẹgun yii ni wọn yoo ti yanju gbogbo ẹjọ to wa nile-ẹjọ lori ọrọ naa, eyi ti yoo le fun ijọba Makinde ni anfaani lati jawe oye le Olubadan tuntun lori.