Faith Adebọla
Ẹgbẹ awọn ọdọ ilẹ Hausa ti wọn n pe ni Arewa Youth Consultative Forum, ti gba Adari apapọ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nimọran pe niṣe ni ko rọra lọọ fẹyinti nidii oṣelu, ko jawọ ninu ilakaka rẹ lati dupo aarẹ orileede yii, tori agbara ati ilera rẹ ko le gbe e, atari ajanaku lẹru Naijiria, ẹni to lokun gidi lawọn n fẹ nipo aarẹ.
Olori apapọ ẹgbẹ naa, Yerima Shettima, lo sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, nigba to n ba awọn oniroyin SaharaReporters sọrọ lori ẹrọ ayelujara.
Shettima ni ohun to pọn Tinubu le ni, to si buyi fun un, ni bo ṣe ti ṣamọna ọpọ awọn ọdọ ati agba kọọkan nidii oṣelu, to si fun wọn lanfaani lati goke agba, o ni iru awọn eeyan to ti da lẹkọọ bẹẹ lawọn reti pe ko fa kalẹ, ki i ṣe oun funra rẹ.
“Mọ bọwọ fun Aṣiwaju o, ṣugbọn emi o ri nnkan to buru nibẹ ti wọn ba lọọ fẹyinti nidii oṣelu, tori gomina ati sẹnetọ ọdun pipẹ sẹyin ni wọn. Mo gbagbọ pe niṣe lo yẹ kawọn aṣaaju Naijiria maa da awọn ọdọ lẹkọọ, ki wọn si fa wọn goke sipo olori, ki wọn le gba iṣakoso lọwọ awọn arugbo ti wọn ti wa lẹnu oṣelu latọdun pipẹ wọnyi.
Ko yẹ ka gbajọba lọwọ arugbo kan ka tun gbe e farugbo mi-in ni Naijiria. Mi o si nipo lati sọ pato ọjọ ori Tinubu, tori ariyanjiyan ti wa nilẹ tẹlẹ lori iye ọmọọdun ti wọn jẹ, ṣugbọn ta a ba wo bi nnkan ṣe n lọ lagbo oṣelu yika aye, oṣelu asiko yii ki i ṣe tawọn arugbo mọ, ọlaju ati imọ ẹrọ igbalode ti gbode, aja iwoyi lo si mọ ehoro iwoyi i le.”
Ni ti ibi ti aarẹ yoo ti wa, Shettima sọ pe ko si nnkan to buru ti aarẹ ba wa lati agbegbe Oke-Ọya, bo ba si jẹ iha Guusu naa ni, o lawọn fara mọ ọn, ohun to gbọdọ jẹ gbogbo eeyan logun ni bi Naijiria yoo ṣe tẹsiwaju, ti iyatọ gidi yoo si wa.
“Mo gbagbọ pe nnkan tawọn agbaagba Oke-Ọya sọrọ nipa rẹ ninu ẹgbẹ Norther Elders Forum wọn tọna, asiko yii kọ lo yẹ ka maa sọrọ ibi ti aarẹ ti maa wa, ko si ibi ti aarẹ ti wa ti ko daa, ki aarẹ naa kunju oṣuwọn, ko si ṣe Naijiria loore lo gbọdọ tẹwọn lọkan wa.
“Ni ti ọrọ ipindọgba, gbogbo aye lo mọ pe ninu eto iṣejọba demokiresi, awọn to ba lero lẹyin ju lọ lo maa n rọnalọ, awọn ti wọn o lero lẹyin kan maa sọrọ jade ni, ko ju bẹẹ lọ.
“Mi o tako ẹya Igbo fun ipo aarẹ, ẹ jẹ kawọn naa wa ẹni to kunju oṣuwọn, ki tọhun si sapa lati lero lẹyin, to ba ti maa ṣe Naijiria loore, o ti daa.”