Adefunkẹ Adebiyi
Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, baba to ti fi ẹrongba rẹ han lati dupo aarẹ orilẹ-ede yii lọdun to n bọ, ti sọ diẹ ninu awọn ohun to lo wa lọkan oun lati ṣe fun Naijiria boun ba di aarẹ.
Ohun akọkọ ti Aṣiwaju loun yoo ṣe ni sisanwo idanwo oniwee mẹwaa, (WAEC), fawọn akẹkọọ to ba wa nipele naa.
O ni ko si obi ti ọmọ rẹ ko ni i le ṣedanwo naa boun ba wọle. Bo ti wu ki obi ọhun talika to, Tinubu sọ pe ọmọ rẹ yoo ṣe Waẹẹki lai sanwo, o ni ijọba oun ni yoo sanwo gbogbo ọmọ to ba to idanwo naa i ṣe.
Bakan naa lo sọrọ nipa bi iṣẹ ati oṣi yoo ṣe kuro ni Naijiria. O loun fẹẹ dije dupo nitori ati tu ṣẹkẹṣẹkẹ iya kuro lẹsẹ kaluku ti ebi n pa ni.
O sọrọ nipa alaafia ti ko si ni Naijiria, Aṣiwaju sọ pe a gbọdọ ṣẹgun awọn janduku gbogbo ti ko jẹ ki ọkan awọn eeyan balẹ. O ni gbogbo iwa ọdaran to gbilẹ yii ko le jẹ ki orilẹ-ede duro, o ni ọkan ninu awọn ojuṣe oun niyẹn.
Ninu fidio kan ni Tinubu ti sọrọ yii, awọn obinrin ẹgbẹ oṣelu APC kan ti wọn kora jọ lo si n ba sọrọ naa. Ẹka iroyin GistReel lo gbe fidio naa jade. Ninu ẹ ni Aṣiwaju ti n rọ awọn obinrin naa pe ki wọn ma ṣe fi ẹgbẹ Onigbaalẹ silẹ o. O ni ki wọn duro ti APC wamuwamu, nitori ẹgbẹ onilọsiwaju ni.
“Igbalẹ ni ami idanimọ ẹgbẹ wa, ami tẹ ẹ si ri lori fila mi yii, ami ta a fi n tun ṣẹkẹṣẹkẹ ni. Ẹyin ni kẹ ẹ tu ṣẹkẹṣẹkẹ aimọkan, iṣẹ ati oṣi atawọn nnkan mi-in.” Bẹẹ ni Tinubu sọ fun wọn.
O tẹsiwaju pe obinrin lo n fori ko jagidijagan yii ju, gbogbo ifipa foju ẹni gbole ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn n koju.
O ni afi ki orilẹ-ede yii toro, bi ko ba jẹ bẹẹ, ko le dẹrun lati tete ri iru Naijiria ta a fẹẹ ni.