Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe, ti ke si Aarẹ orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, lati ma ṣe fakoko kankan ṣofo mọ lori abadofin eto idibo ti awọn aṣofin apapọ n ṣatunṣe si lọwọ, o ni ko yaa buwọ lu abadofin naa, ki ajọ eleto idibo atawọn araalu le tete jẹ kawọn ofin tuntun inu rẹ mọ wọn lara ki eto idibo gbogbogboo too waye lọdun 2023.
Lori eto ori tẹlifiṣan Channels kan ni Fayoṣe ti sọrọ yii l’Ọjọruu, ọsẹ yii, o ni ko sohun to tun yẹ ko da Buhari duro mọ lati sọ kinni ọhun dofin.
Fayoṣe ni “O ti fẹẹ mọ Buhari lara lati maa wi awawi ti ko fi ni i buwọ lu awọn ofin to ṣe pataki forileede wa. Ṣẹ ẹ ranti pe ki idibo ọdun 2029 too waye, o yẹ ko ti buwọ lu abadofin yii, ko ti sọ ọ dofin, ṣugbọn niṣe lo n ṣawawi oriṣiiriṣii nigba yẹn.
“Mi o sọ pe nnkan tawọn aṣofin apapọ ṣe daa tabi ko daa, ṣugbọn o yẹ ki Buhari maa ronu orukọ toun fẹẹ fi silẹ fawọn eeyan lati maa fi ṣeranti oun, pe oun lo jẹ ki eto idibo tubọ ja geere si i.
“Bi Buhari ba tun kọ lati buwọ lu ofin yii lẹyin tileegbimọ aṣofin apapọ ti pari atunṣe si i, o yẹ kawọn ọmọ Naijiria tete fura si i.
Tẹ o ba gbagbe, lẹyin nnkan bii oṣu kan tawọn aṣofin apapọ ti taari abadofin tuntun naa si Aarẹ Buhari lo da a pada fun wọn, o ni awọn apa kan ninu ofin naa, paapaa eyi to rọ mọ ilana gbangba laṣa i ta tawọn ẹgbẹ oṣelu yoo maa fi yan ọmooye ẹgbẹ wọn, ko ba ofin ilẹ wa mu daadaa, o ni ki wọn lọọ tun kinni naa wo, ko si buwọ lu u.
Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, tawọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin ati awọn aṣofin agba ti pada sẹnu iṣẹ lẹyin isinmi wọn ni wọn ti bẹrẹ si i yẹ abadofin naa wo, wọn si ti n ṣe awọn atunṣe to yẹ, pẹlu ireti lati fi i ṣọwọ si Aarẹ laipẹ fun ibuwọlu rẹ, ki wọn le lo ofin naa lasiko eto idibo gbogbogboo ọdun 2023.