Florence Babaṣọla, Oṣogbo
‘Anfaani wa fun ẹnikẹni to ba fẹẹ dije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ta ko mi, ki ẹni to ba fẹẹ ṣe bẹẹ lọọ gba fọọmu.’ Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, lo sọ eleyii di mimọ, nigba to n fi ero ọkan rẹ han nibi eto ironilagbara kan ti ajọ Ogundokun Vanguard ṣagbekalẹ rẹ niluu Iwo.
O fọwọ sọya pe oun ko bẹru ibo abẹle, ninu eyi ti wọn yoo ti mu ẹni ti yoo koju awọn oludije latinu ẹgbẹ oṣelu to ku lasiko idibo ti yoo waye ninu oṣu keje, ọdun yii. O ni oun nigbagbọ pe oun ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC yoo tun fa kalẹ.
Oyetọla ni nipasẹ awọn iṣẹ takuntakun tijọba oun ti gbe ṣe laarin igba toun ti de ori aleefa, ko ni i si iṣoro kankan.
Gomina, ẹni ti alakooso apapọ fun ipolongo ibo rẹ, Israel Famurewa, ṣoju fun nibi eto ti wọn tun ti fontẹ lu saa keji fun un parọwa si awọn alatilẹyin rẹ lati mura silẹ fun idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ẹnikẹni to ba fẹẹ gba fọọmu erongba lati dupo gomina le lọọ gba a. Ko si wahala rara ninu idibo abẹle, a ni idaniloju pe a maa jawe olubori.”
Oyetọla dupẹ lọwọ ajọ naa fun ifọwọsowọpọ wọn pẹlu ijọba nipa nina owo ara wọn fun igbaye-gbadun awọn eeyan agbegbe naa.
Nigba to n sọrọ lori bi awọn kan ṣe n sọ pe iha Iwọ-Oorun Ọṣun lo yẹ ki ipo gomina pada si lọdun 2026, gomina ke si awọn eeyan naa lati ṣiṣẹ fun aṣeyọri rẹ, ki eleyii baa le ṣee ṣe fun wọn.
Oludasilẹ ajọ naa, Oloye Abiọla Ogundokun, sọ pẹlu idaniloju pe wahala to n ṣẹlẹ laarin Gomina Oyetọla ati Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla yoo rokun igbagbe laipẹ.
O ṣalaye pe lati ọdun 1976 ti oun ti bẹrẹ ajọ naa lasiko ti oun jẹ kanselọ nipinlẹ Ọyọ atijọ, ọkẹ aimọye anfaani lawọn araalu si ti jẹ nipasẹ rẹ.
Oludamọran pataki fun Gomina Oyetọla lori ọrọ oṣelu, Ọnarebu Debọ Badirudeen, sọ pe gbogbo awọn eeyan ilu Iwo ni wọn ti fẹnuko lati dibo wọn fun Oyetọla, ki anfaani le wa si Iwọ-Oorun lọdun 2026.