Faith Adebọla
Minisita fun iṣẹ ode ati eto ile gbigbe nilẹ wa, Amofin agba Babatunde Raji Faṣọla, ti gboṣuba sadankata fun iṣakoko Muhammadu Buhari, paapaa lori ipese ohun amayedẹrun fawọn ọmọ Naijiria, o ni ijọba naa ṣe daadaa gidi, o ju torileede Amẹrika lọ.
Ilu Kano, nipinlẹ Kano, lapa Oke-Ọya orileede yii, ni Faṣọla ti sọrọ ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lasiko to sọrọ nibi eto kan ti wọn gbe kalẹ lati la awọn araalu lọyẹ lori aṣeyọri iṣakoso All Progressive Congress (APC) eyi ti Buhari n dari.
Faṣọla ni, “Ẹ jẹ ki n fi da yin loju pe iṣakoso APC, eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari n dari lọwọ yii ti ṣaṣeyọri gidi lori ipese awọn nnkan amayedẹrun faraalu, koda, ijọba orileede Amẹrika ṣi n le aṣeyọri naa ni, wọn o ti i le ba.
“Ni oṣu Kejila, ọdun 2021 tọ kọja yii, a ti pari awọn ọna maroṣẹ kaakiri origun mẹrin orileede yii, ti aropọ awọn ọna naa gun to kilomita ọgọrun-un mẹsan-an aabọ (941 km).
Ni ipinlẹ Kano yii, gẹgẹ bii apẹẹrẹ, ọna mọkanlelogun ọtọọtọ ni iṣẹ n lọ lori ẹ, laarin ilu Kano ati lawọn adugbo kan.
“Ṣaaju ijọba APC, ọjọ wo lẹ le ranti pe ijọba apapọ pari ọna kilomita aadọta nibikibi lorileede yii?
“Lara ayipada rere ta a ṣeleri fawọn ọmọ Naijiria lọdun 2015 pe a maa mu wa lo ti n ṣẹlẹ yii. Tawọn eeyan ba n sọ pe ọkan naa ni awa ati awọn araabi, irọ ni, a o ki i ṣe ọkan naa. Niṣe lawọn n ji owo ko, ti wọn n ko o lọọ siluu oyinbo, ṣugbọn awa n gba owo pada, a n na an sori ipese ohun amayedẹrun faraalu ni.”
Bakan naa ni Faṣọla sọ pe labẹ ileeṣẹ iṣẹ ode toun n dari, awọn iṣẹ akanṣe to ju aadọta le lẹgbẹrin (850) lọ, ni iṣẹ n lọ lori wọn ni rẹbutu, titi kan awọn ọna aarin ilu, ọna marosẹ, oniruuru afara, ati kọta ti ọgbara yoo maa gba, ipinlẹ mẹrinlelọgbọn si lawọn iṣẹ naa ti n lọ lọwọ, gẹgẹ bo ṣe wi.