Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Ọlasunkami Oluwọle, ti wa ni ikawọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o mọ nipa iku to pa ale rẹ, Biọla Soyinka, sinu otẹẹli kan niluu Oke-Igbo.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, iṣẹ mẹkaniiki ni Oluwọle n ṣe, o ti ni iyawo, bẹẹ lo si ti bimọ meji silẹ.
Ọjọ kẹta, oṣu ta a wa yii, ni wọn lo ranṣẹ si Biọla to jẹ ololufẹ ikọkọ rẹ, ẹni to n gbe niluu Eko lati waa ki i l’Oke-Igbo.
Bo ṣe de lo lọọ fi obinrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji naa pamọ sibi kan tawọn mejeeji ti maa n pade loorekoore lati gbadun ara wọn.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja, ni baba ọlọmọ meji ọhun pe ọkan ninu awọn mọlẹbi ale rẹ sori aago pe Biọla ti ku lẹyin to deedee ṣubu lulẹ lojiji ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa.
Oluwọle ṣalaye pe oun gbe e lọ sileewosan lẹyin to daku latari bo ṣe subu lulẹ, nibẹ lawọn dokita si ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.
Ẹgbọn Oloogbe ọhun kan, Ọgbẹni Akeem Jinadu, to bawọn oniroyin sọrọ ni kayefi patapata lohun to ṣẹlẹ naa si n jọ loju awọn.
O ni ni kete ti Oluwọle pe awọn lawọn ti sọ fun un pe ko maa gbe oku ọmọ awọn bọ l’Ekoo, ṣugbọn to ni ko sowo lọwọ oun lati fi ṣe bẹẹ.
O ni lẹyin tawọn foju ara awọn ri oku Biọla lawọn too mọ pe irọ ni ọkunrin naa n pa lori ohun to ṣokunfa iku rẹ nitori pe ọkan-o-jọkan egbo lawọn ri lara rẹ, leyii to fihan pe ṣe ni wọn lu u tabi fun un lọrun pa.
Jinadu ni ẹgbẹrun lọna ọtalelugba din mẹwaa Naira (#250, 000) lawọn ẹbi si n ko jọ lọwọ lati fi ṣayẹwo iru iku to pa Biọla.
O ni ni kete tawọn dokita ti fidi iku ọmọ awọn mulẹ nileewosan ni Oluwọle ti fẹẹ sa lọ, kawọn eeyan too ri i mu, ti wọn si fa a le awọn agbofinro lọwọ.
Ọkunrin to n gbẹnusọ fawọn ẹbi oloogbe ọhun ni ko si nnkan mi-in ti awọn n beere fun ju idajọ ododo lọ nitori pe eyi nikan ni ko ni i jẹ ki iku ọmọ awọn ja si asan.
Wọn ti gbe afurasi ti wọn fẹsun kan ọhun kuro niluu Oke-Igbo, wọn ti fi i ṣọwọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ.