Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alaga igun ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn pe ni The Osun Progressives (TOP) nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Ọṣun, Solomon Alatayọ atawọn mẹrin mi-in, ni ile-ejọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ naju lọgba ẹwọn Ileṣa lori ẹsun igbiyanju lati paayan ati jijẹ ọmọ ẹgbẹ to tako ofin.
Awọn ti wọn tun ko wa si kootu pẹlu Alatayọ ni Alinlade Abayọmi, ẹni ọdun mejidinlogoji, Sodiq Atitẹbi, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Azeez Adejinmi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Ṣiju Oyewumi to jẹ ẹni ọdun mejidinlaaadọrin.
Ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wahala bẹ silẹ nibi ipade kan ti awọn TOP ṣe niluu Ikirun to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ti awọn igun mejeeji; iyẹn TOP ati IleriOluwa.
Ni kootu ni wọn ti fẹsun kan awọn olujẹjọ pe wọn gbiyanju lati pa Ọgbẹni Fasasi Asimiyu lasiko wahala naa.
Agbefọba, Jacob Akintunde ṣalaye pe ṣe ni Alatayọ atawọn olujẹjọ yooku huwa laabi yii laago meji ku iṣẹju mẹẹẹdogun lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun yii, lasiko ti wọn kora wọn jọ lọna ti ko bofin mu.
O ni wọn tun gbiyanju lati pa Asimiyu lasiko ti wọn n fi ada da batani si i lara, eyi to lewu fun alaafia agbegbe.
Nitori idi eyi, Akintunde sọ pe iwa awọn olujẹjọ tako ipin okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin, okoolenirinwo ati ọtalenirinwo o din mọkanla abala ikẹrinlelọgbọn ofin ipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin ti awọn maraarun sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan wọn ni agbẹjọro wọn, Ọlatunbọsun Ọladipupọ, rọ kootu lati fun wọn ni beeli.
Ṣugbọn agbefọba tako arọwa agbẹjọro olujẹjọ, o ni awọn ọlopaa ṣi n wa awọn yooku ti wọn jọ huwa naa, bi kootu ba si fun wọn ni beeli, wọn aa dabaru iwadii.
Ninu idajọ rẹ, Majisreeti Asimiyu Adebayọ paṣẹ pe ki wọn maa ko awọn olujẹjọ lọ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii, ti idajọ yoo waye lori boya wọn lẹtọọ si beeli tabi bẹẹ kọ.